Smiley face

Meji nínú àwọn olè Ofa tí de òpin ìrìn àjò wọn

Ọwọ́ àwọn ọlọ́pàá Nàìjíríà tí tẹ àwọn méjì míì tí wọn wá lára àwọn adigunjale tí wọn ṣekú pa àìmọye ènìyàn l'Ofa.

Ohun tí a gbọ ni wí pé, Abba Kyari, ọlọ́pàá ọlọtẹlẹmuyẹ ti wọn gbéga laipe yii fún àwọn iṣẹ́ takuntakun tó ṣe sẹ́yìn, lo mú àwọn ọ̀daràn yìí kan náà.

Gẹ́gẹ́ bí atẹjade ileesẹ ọlọ́pàá ṣe gbé kalẹ, àwọn ènìyàn bí àádọ́ta ni àwọn adigunjale yìí fi èmi wọn ṣòfò nínú ijamba to wáyé l'Ofa níbi wọn ti ji àìmọye owó banki salọ.

Síwájú sii, àwọn ilé ìṣe ọlọ́pàá sì ń rọ àwọn ará ìlú láti má jẹ ki etí wọn di nígbàkúùgbà tí wọn ba kefin àwọn ọ̀daràn yìí níbikíbi nitori ọ̀pọ̀ wọn lo sí wa lórí ere ṣíṣá ti ọwọ àwọn ọlọ́pàá kò ti bàá.

Bákan náà ni gomina ìpínlè Kwara, Ọ̀gbẹ́ni Abdulfatah Ahmed ṣe ìlérí milionu marun-un owó náírà (N5m) fún ẹnikẹ́ni to bá le rán wọn lọ́wọ́ láti mú àwọn adigunjale tí wọn ṣe ijamba lọjọ karùn-ún oṣù kẹrin ọdún 2018.

Lópin ohun gbogbo, ẹ kéde rẹ fún àwọn ọ̀dọ́ wí pé idaran kò pé. Bi ẹ kò bá mọ Pablo Escobar nílùú Colombia 🇨🇴, ṣebi gbogbo wa la gbọ́ nípa Oyenusi, ògbólógbòó adigunjale ni Ìjẹ̀bú Ode? Bí Oyenusi ṣe lówó, ṣe lòògún to, ó padà kú ikú ìbọn naa ni. Òfo lórí òfo ni!

Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment