"Bàbá mi má ń fẹnu fà ọyàn mi, bákan náà lo bá mi ni ajosepo fún ọdún mẹ́rin"
Ọmọbìnrin ẹni ọdún méjìdínlógún (18) tí bàbá rẹ̀ n bá lojosepo fún ọdún merin lo tí farahan níwájú ilé ẹjọ́ lánàá, 23/05/18.
Baba ọmọ yìí, Ogbeni Folorunso Olúwáseun, ẹni ọdún mejilelaadọta (52), tí wọn fura si wí pé ó ń bá ọmọ rẹ sún yìí là gbọ wí pé ó ń ṣe eléyìí láti rí wí pé ojú ara ọmọ rẹ̀ fẹ dáadáa.
Ọmọbìnrin tí wọn fi orúkọ bo lasiri yìí ló ń ṣe àlàyé fún onidajọ Justice Sybil Nwaka, ni ilé ejò àkànṣe tí ipínlẹ̀ Èkó gbé kalẹ ni Ikeja, Ikeja Special Offence and Domestic violence Court wi pe, láti ìgbà tí òun ti wá ní ọmọ ọdún méjìlá (12) ni bàbá òun ti n bo òun mọ́lẹ̀ ní ile àwọn tó wà ní Ikorodu eléyìí tí n ṣe láàárín ọdún 2012 sì 2016.
"Ni akoko ti bàbà mi bá ń bá mi sún, a má fi ọwọ́ fún ọyàn mi, yóò tún má fẹnu fàá, yóò sì ma sọ wí pé òun ṣe help fún mi ni".
Nigba to di ọdún 2016 tí ìyà wọn wá sílè to rí àṣírí ohun tó n ṣẹlẹ̀ lo ko àwọn ọmọ rẹ lọ siluu Ìbàdàn.
Ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bí awijare Ogbeni Folotunsho, ó ní irọ́ lásán ni ọ̀rọ̀ náà. Ó ni ọmọ òun un gbìyànjú láti parọ mọ òun ni látàrí wí pé òun má n báawí wí pé ko tọju àwọn àbúrò rẹ dáadáa.
Ọmọbìnrin yìí to tí bẹ̀rẹ̀ ìṣe tisa nílùú Ìbàdàn yìí lo sọ ìtàn ayé rẹ fún oga ilé ìwé wọn, oga iléèwé naa lọ sí rán an lọ́wọ́ láti fi ẹjọ́ náà sún ẹ̀ka ilé ìṣe ìjọba Èkó tí wọn rí sì irú iṣẹlẹ bẹẹ.
Jù gbogbo rẹ lọ, ìwádìí si ń tesiwaju láti mọ okodoro ọ̀rọ̀ náà.
0 comments:
Post a Comment