Smiley face

Apeere "Example"

Mo feran John Maxwell gidi gan-an. Agbalagba oluko ti ki i lo efun ko to koni logbon agba ni. Ogbon dara looto, sugbon ko si ohun ti a le fi we laakaye, laakaye ni baba ogbon.

Aimoye iwe John Maxwell lo maa n ba mi sun, ba mi ji lori ibusun mi. Nitori mo sakiyesi wi pe gbogbo oro re rekoja aroso lasan, iriri ati isele gidi lo maa n gbe idanileko re le lori nipa imo isakoso, oludari ati alamojuto

Opolopo idanileko re ni Alufa Chris Oyakhilome jeri si nipa ohun ti ipo oludari gunle.


Tani won pe ni Asaaju tabi Olori?

Asaaju ki se eni to wa ni iwaju patapata ti gbogbo eniyan n too leyin bi oromadiye se n tele adiye agbegbo. Asaaju ki i se eni to joko sori oke gagara ti gbogbo eniyan n wari fun bi oosa akunlebo. Bakan naa ni asaaju ki i se eni to n gbe igbe aye to dara ju awon yoku lo.


Asaaju tabi Olori je enikan to n ran arayoku lowo lati je eni iwaju. Asaaju je eni to n le iwaju lati pa ona mo tabi lati la ona fun awon ara yoku lati le ri ona gba.

Asaaju leni to n tiraka lati mo ohun to le tabi ruju pelu ero lati fi imo naa han awon oloju dudu ni ona to rorun ki awon naa si le di onimo.

Asaaju ki i seni ti n ja fun ara re lati ri ona lo bikose eni ti n ja fun ara yoku lati tayo tabi lati moke. Asaaju leni to fi ara re jiya fun igbadun awon ara yoku.


Eyi gele ni Jesu se lati fi ara han gege bi apeere asaaju rere. Jesu Kristi ku ki awa le ni iru emi iye ti Olorun oga ogo ni, 'Zoe'. Agbara nla ni oro re sugbon o gbe kale ni ona to rorun ki oye oro naa le ye wa.

Olukoni bi ti Jesu ko po rara, Adari bi ti Jesu lo sowon, Olugbala bi re ni o pe meji.

E ku Odun Ajinde!
Sent from my BlackBerry wireless device from MTN
Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment