Smiley face

Ere Omo Yahoo!

Onikaluku ni o juwe igbe aye to fe gbe. Ohun to wu eda, leda figba re loo. A mo ohun to damiloju ni wi pe ohun kaluku gbin ni o ka bi ere ajemonu tire.

Amohunmaworan agbaye pade gbe Nick D'Aloisio jade faraye ri. Aramonda omo odun meta din logun ti tewo gba owo to to ogbon milionu dola owo ile America ($30 million) latari ara otun ohun elo ayarabisa ti Yahoo! ra lowo re.

Yahoo! o kan raja re lasan, won tun so Nick D'Aloisio domo won ni ko maa bo loke wa ba awon agbalagba jeun.

Nick D'Aloisio o sa deede han lori agbagbe, ojo ti n pagun ojo ti pe. Iwadii fi ye wa pe ati omo dun mejila ni Nick D'Aloisio ti n gbiyanju boo lohun elo tuntun komputa eyi ti o mu iroyin rorun fun gbogbo araye ti bere lati owo re.

Bi gbogbo egbe re n re pati, Nick D'Aloisio joko sile ronu ibi ti ohun tun gbe ogbon ohun gba.


Nick D'Aloisio ti tewo gba ere ti e lonii. Kini o lero wi pe ni je ere ohun to n gba opolopo akoko re lonii to ba dola?

Sent from my BlackBerry wireless device from MTN
Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment