Smiley face

DELETE JE ORO AGBARA

Orisii oro geesi kan ti a mo si 'Delete' wa lara awon oro to lagbara ju laye. Bi o ti le je wi pe o ti di ede ojoojumo, sibesibe lilo ti a lota ko pawa ata da.

Awon eniyan ti ko ba ni aridaju nipa iru eniyan ti won je tabi ohun ti won mo ki i se amulo orisii oro agbara yii. Awon eniyan ti won ko gbagbo ninu ara won tabi isowo awon eniyan ti won o lokan akin ki i lo 'Delete'.

Nje kilo mu delete je ohun agbara tabi ti o fi je wi pe ki i se orisii oro ti opo eniyan n lo?

Delete gege bi ede geesi tunmo si ki eniyan pa ohun kan re tabi ju nu-un. A maa n lo ni ibamu pelu ohun kan ti a ko lo mo tabi ohun ti ko wulo fun wa mo.
 
Mo se alabapade oro yii fun igba akoko nigba ti mo bere eko kiko nipa ero komputa ni odun 2001.

Oluko ero komputa wa maa n so fun wa nigba naa wi pe delete je ohun elege ati wi pe ani lati ri idaniloju wi pe ohun taa ni i lo mo ni a fe delete re saaju ki a to pinnu ati se bee nitori wi pe gbogbo ohun ti a ba delete ko ni a le ri pada mo.

Iberu o seese ka maa ri iru nnkan bee pada mo ki i je ki opolopo eniyan lo delete nigba naa ati wi pe aidara eni loju naa tun kun.

Ninu igbesi aye ede, mo sakiyesi wi pe delete yii tun se pataki bi o tile je wi pe iwomba eniyan perete lo n se amulo re ninu igbesiaye won.

Eniyan ti ko da ara re loju nipa ibi to n lo laye, aimoye ipinnu ni iru eni bee ko ni i le se.

Ore ti o ba teniije ki i se ohun ti i nira ati mo rara. Iwa to le deni lona ogo ki i se igba taba to beere lowo wooli ko to le ye ni. Agbara ni delete, awon eniyan akin ni i se amulo re nigba ti won ba ridi pataki ati se bee ki won le tesiwaju ninu erogba won.

Ewu meji lo romo Delete:

Lara ohun to ye mi yeke ni wi pe ti eniyan ba ko lati delete awon ohun to ye ko delete ninu igbesiye aye re afaimo kii iru nnkkan bee maa pada delete iru eni bee lawujo awon alaseyori.

Latari aini oye to peye, opolopo awon eniyan ti delete ohun iyebiye eyi to mu irinajo won ati goke maa fa bi igbin.

Olayemi Oniroyin, alaye oro mbo, mo kan ni ki n feyi side alaye lasan ni. E ku ikale.
Sent from my BlackBerry wireless device from MTN
Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment