Lonii ojo karun-un osu keta odun egberun meji ati metala, iroyin kan mi wi pe awon omo egbe agunbaniro tuntun yoo teri wo ibuba won lonii fun igbaradi ati sinru ilu baba won.
Idunnu ati ogo lo je fun eni ti o keeko pari, iko okan soke ati ipaye fun agunbaniro ti won so si ona jinjin rere.
Mo ranti igba ti oye naa kan mi, bi o tile je wi pe Kogi ko wu mi lo ni ibeere pepe, sugbon tiduntidun ni mo fi juwo fun iya wi pe mi o ni pe pada wale.
Iru ojo oni, awon ti won ti se agunbaniro o maa se iranti igba ti won gege bi awon asese gba wole se n se kurukere.
Apeere eyi lo koko mu ara fu mi nigba ti mo ri okan lara awon ore mi ori ero Blackberry ti n gbe awon igba agunbaniro re sore Aworan Ifihan re gege bi ohun iranti pelu akole to so wi pe " Igba naa re bi ana yii" mo rerin muse. Mo se iranti igba akoko ti emi naa de ibuba awon agunbaniro ni Asaya ni ilu Kogi, mo si n ro ohun ti o le maa rekoja lori okan awon ti won tun sokale sibe lonii yii.
Lehin ogun iseju, ore mi yii tun yii akole re pada, bakan naa lotun pa awonran afihan re da si eyi ti o ya nigba to wa ni yara ikekoo ni ile iwe giga. Bo se ko akole naa gele lo wa ni isale yii:
"I'm still waiting for the day I will actually use: {x²+2x(?cos60) -6y³(?3z) +tan?=5z}(asume tan?= 0.8660) to solve real life problems #:-s"
Itunmo :
"Mo si n duro de ojo kan pato ti n lo: {x²+2x(?cos60) -6y³(?3z) +tan?=5z}(ka gba wi pe tan?= 0.8660) ti n fi tan isoro aye gidi."
Opolopo ogbon oun imo ni won ko wa ni yara ikawe ti o si je wi pe ibe naa ni awon ogbon ati imo yi mo.
Okan mi ku fun ogbe, nitori iru ero yii ti so si mi lokan ri. Aimoye igba ni mo n beere orisii ibeere kan naa yii ti o si je wi pe gbogbo igba naa lo n pesi je.
Kilode ti o fi je wi pe opolopo nnkan ti a nko ni ko wulo fun awujo wa ti ode oni, a si n tesiwaju ati maa sakopo iru eko bee mo awon eko inu
korikuloomu wa? Olugbala lo ye ki awon akekoo ti won jade ile iwe je si awujo lowo isoro ti n koju won. Sugbon kaka ko san lara omo iya aje, abo lo tun n bi lomo.
Awon ti o ye ki won tan isoro awujo wa, isoro ni won tun un je fun awujo. Amukun eru re wo, won ni oke ni e n wo e wole.
Olayemi Oniroyin, ori oke yii ni emi naa duro si nigba ti mo n reti ojo Mofiimu Afarahe, Akude gboluhun, Oju odu meridinlogun o dowo fun mi loju aye gidi.
Sent from my BlackBerry wireless device from MTN
0 comments:
Post a Comment