Smiley face

Atelewo Mi: Ayanmo Mi

Atelewo eni kii tan ni i je
Mo ranti igba ti mo wa ni kekere- igba ti mo maa n sere iyepe. Ko si igba ti oko baalu ofurufu koja ti ki i wu mi. Maa na enu mi soke pariwo ko wa gbe mi lo si ilu oyinbo. Nitori lara ero mi ni lati mo ilu kaakiri agbaye.
 
Gege bi ero omo kekere, mo ro wi pe ona to ya ju lati mo opolopo ilu ni lati di awako baalu. Boya nipase kiko awon ero kiri mo le gba ibe mo orisiirisii ilu ti mbe lagbaye. Sugbon otito oro ni wi pe ki i se nipa didi awako baalu, bi ko se nipa jije ohun to ye ki n je ni iru igbe aye to wu mi file temi lowo.
Lara ohun ti mo tun nife si nigba ti mo n dagba a bo ni ki n ma wadii ati mo nipa ohun ti n lo ni agbegbe mi. Yala nipa oro to lo lowo, oro oselu, amuludun ati ere idaraya.  Sugbon iroyin ere idaraya je ohun ti mo tele julo, paapaa julo ere boolu alafese gba.
Kosi ohun to pamo fun mi nipa owo tabua ti opolopo awon agba boolu n gba ati igbe aye ti won n gbe. Owo ti okan n gba ninu won laaarin wakati meji, elomiiran o ri to papo fun odindi odun meji. Oko bogini, ile alarinrin, faaji lotun-faaji losi, okiki ati bee bee lo.
 
Ojo kan ni mo ji mo si pa ero mi po lati di agbaboolu. Owo to wa lowo mi o to ra bootu, mo lo ko kanfaasi egbon mi kan ti ko wo mo, mo tun se. Mo ba mu ona pon, odi ile iwe Obakinbiyi keji ti o wa ni ore meji, ilu Ibadan.
 
Awon egbe agbaboolu kan wa nibe, mo lo dara po mo won. Bee ni mo si di agba boolu ojiji. Sugbon nigba to ya, ko wu mi lo mo, ki lo si fa?

Walahitalai, ki n maa paro fun yin ko ro mi lorun ni. Gbogbo igba ti mo fi n gba boolu yii mo kan n tiraka ni.
 
Mo fori ti bi e ni wi pe ko nipe bo si mi lowo, sugbon iro ni mo pa. O pada da mi loju wi pe ki i se boya boolu gbigba wa ninu mi gan-an sansan, emi ni mo n tiraka a ti wonu boolu lo. Idi ni ti mo fida kanfaasi onikanfaasi pada ree ti mo si jooko mi jeje.
  
Opolopo awon eniyan ni won sare ki owo won ba orisii igbe aye to wu won gbe- okiki, owo ati jije eniyan pataki lawujo. Sugbon ko si bi owo eda se fe te iru igbe aye to wu eda gbe ayafi ti o ba to se awari iru igbe aye to wa lowo gan-an. 

 Ohun to ni i lo lati moke laye, kosi nita, inu re lo kale si. Ojuse re ni lati mu sita. Gbogbo eroja to ni i lo lati di iru eniyan to wu o lati da pata lOba oke ti gbe sinu re. Ojuse re ni lati se awari ebun to ni. Se itoju ebun naa bi igba eniyan n to omo dagba. Ko ina mo nidi bi igba eniyan gbe ounje sori ina. Mo fi da o loju, o ti n su mo ibi to n lo iwo lo o fura.
E ku ikale.
Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

2 comments:

  1. oro agba lati enu omo agba....oloyemi e ku ise opolo, olorun a ma fun e se (Amin)....eledua to seda ka lu ku ti mo ohun ti a ma gbe ile aye se. Adura ni gbogbo ikan ni Aye yi. o digba kan

    ReplyDelete