Smiley face

Aare Goodluck Ko Milionu Meji Si Apo Enikookan Omo Golden Eaglets

Aare Goodluck Jonathan ti se ileri Milionu meji fun enikookan awon omo Golden Eaglets ti won jawe olubori ninu idije boolu agbaye to waye.

Aare so wi pe aseyori yii kii se ti Naijeria nikan, bi ko se ti ile adulawo lapapo. Aare tun fi kun un wi pe ijoba ohun yoo fi ami eye da awon ti won kopa ribiribi ninu aseyori idije boolu agbaye naa lola.

Lara awon eni ti Aare se ileri ami eye fun ni olukoni egbe agba boolu naa eleyii ti aare ko milionu meta si lapo fun ise nla to se.

Aare tun pe awon ile ise nlanla lati se iranwo fun awon ogo tuntun yii lati fi dun won ninu nipa oruko ile wa ti won so dotun.
Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment