Bi o tile je wi pe won ti n fe ara won bi nnkan bi odun mejo seyin, Peter Okoye ati Lola Omotayo pada fi edidi di ife won lori ni ojo ketadinlogun osu kokanla odun ta a wa yii.
Lara awon aheso ti awon eniyan n so kiri igboro nipa wi pe odun ti Lola gba lowo oko re ko din ni odun mewaa ni Lola Omotayo ti fun ara re fesi oro pada, sebi isoro-n-gbesi gege bi oro awon Yorubawa.
"Nibi ti ife ba duro si, ojo ori ko ni itunmo kankan rara. Gege bi olokoowo agbase se, mo gba ise agbase lowo British American Tobacco lati pate ariya fun igbelaruge oja won, P-Square si je okan lara awon olorin ti won wa sere lojo naa.
Ibe lati pade to si beere nomba ibanisoro mi eleyii ti mo ko jale lati fun un. Mo so fun wi pe to ba fe mi looto ko fun ara re wa nomba mi kan eleyii to pade se.
Bi a se bere ree, ti ife wa si n gbooro sii.
Ojo ori ko se pataki, ife ti a ni si ara wa lo so wa di okan soso" Lola Omotayo
Subscribe to:
Post Comments
(
Atom
)
0 comments:
Post a Comment