Ti won ba ni ajura wa lo bi ti ijakadi ko.
Sugbon, e duro na, sebi ki awon omo ile igbimo asofin maa dobale niwaju gomina ha ni?
Labe ofin gan-an, o ye ki gomina maa sababa awon omo ile igbimo asofin ni. Nitori ti gomina ba gungi koja ewe, awon omo ile igbimo asofin ni won lagabara labe ofin lati re gomina ni ifase.
Sugbon bayii, esuru ti in laja ti aja ko si le duro boju weyin. Orisiirisii ni i sele labule wa.
Emi o mo ohun ti awon omo ile igbimo asofin ipinle Imo n ba gomina won so to fi wa dogun ohun ti a n kunle soro.
Aworan oke yii lo n se afihan Onarebu Stan Dara ati Ike Anuka ti won je omo ile igbimo asofin Ipinle Imo ti won kunle n rojo niwaju Rochas Okorocha ti o je gomina Ipinle Imo bakan naa.
Eni ti o joko legbe gomina ni olori ile igbimo asofin Ipinle Imo, Uwajumogu.
Subscribe to:
Post Comments
(
Atom
)
0 comments:
Post a Comment