Ati igba ti mo ti gbo oro naa ninu eti mi, ni mo ti so di asaro mi. Eyi si je opakutele ti mo fi maa n dupe lowo Olorun ni gbogbo ojo.
"Mo le ma ti de ibi to wu mi i de, sugbon ohun to daju ni wi pe mi o wa nibi mo ti maa n wa tele"
Dandan ni fun onikaluku lati mu okan won le, ati lati bori isorokisoro ti o le maa koju eda laye.
Ipo ti orile-ede wa wa lonii le ba ni lokan je pupo, sugbon ohun to daju ni wi pe igbagbo wa le mu wa bori ni ikeyin ohun gbogbo.
Ki enikeni ma se so ireti nu, ise Oluwa koja ero okan eda. Agbara si ni oro Re. Olorun le se ohun gbogbo nigba gbogbo laisi idiwo tabi idina rara.
E maa se je ki igba yii bu omi tutu si yin lokan abi ohun ti e n la koja so yin di alaini igbagbo ninu Olorun. E mu okan yin le pelu adura si Oluwa orun ati aye.
Mo ti gbadura si Olorun oga ogo fun yin nipa osu December wi pe ko payin mo ninu alaafia ati abo to peye. Mo si gbagbo wi pe adura mi ti gba.
Mo ki yin kaabo sinu osu tuntun, osu alayo. Mo si dupe fun atileyin yin nigba gbogbo. Sebi eyin ni ore mi, eyin ni ololufe mi, eyin naa si ni ebi mi.
E se gan-an lopolopo.
Olayemi Oniroyin
Subscribe to:
Post Comments
(
Atom
)
0 comments:
Post a Comment