
Nibayii, Aare ile Naijeria, Goodluck Jonathan ti fi alaga egbe PDP nigba kan ri, Alhaji Bamanga Tukur je alaga igbimo ajo oko oju irin ile Naijeria (Chairman Board of the Nigerian Railway Corporation).
Ti e ko ba gbagbe, ose to koja ni agbalagba oloselu yii kowe fi ipo re sile gege bi alaga leyin opolopo darudapo to ti n waye ninu egbe PDP ti won si fi gomina Ipinle Bauchi nigba kan ri, Adamu Muazu ropo re.
Bi o tile je wi pe ipo alaga lo bo sonu lowo Alh Bamanga, ipo alaga naa lo tun pada bo si lowo. O kan je wi pe aga ju aga lo ni. Se e mo wi pe eniyan ko le fi aga 'Kusinsia' we apoti lailai.
0 comments:
Post a Comment