Smiley face

Awon Apeja Ti Ri Orisii Eya Eja Tuntun Ni Ilu New Zealand



Airin jina lai ri abuke okere. Bi eniyan ba rin titi, eniyan yoo ri ibi won ti n fi odo ibile jeun.

Okunrin apeja kan ni ilu New Zealand lo kofiri orisii eja aramonda kan ni arewa erekusu Karikari Peninsula eleyii to so wi pe o koko ba oun leru eleyii to mu oun sa seyin ki oun to tun pada lo se ayewo eja naa leti omi to ti n sere.
 
 
Gege bi oro Stewart Fraser to je apeja to ri eja naa se so, o ni bi eniyan ba mu eja yii dani, eniyan le ri odikeji re ati wi pe eja naa ki i se eja onijamba rara tabi orisii eja to le panilara.
Bi o tile je wi pe ko si eni to le so wi pe oun ti ri iru eja yii ri, sibesibe awon onimo nipa ohun abemi inu omi se apejuwe oruko eje naa gege bi 'Salpa maggiore'.
 

 
 

 
Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

1 comments: