Smiley face

Jay Z Ati Beyoncé Dana Sun Grammy


Awon Yooba loni odoodun laa rorogbo, odoodun la rawusa, todun ba ti de laa ri omo obi lori ate. Odoodun ni ayeye ami eye Grammy agbaye maa n wa lati bu ola ati iyi fun ise orin opolo to fakiki lagbaye, bakan naa lo se ri lana ode yii ni Los Angeles ni ilu Amerika nibi ti ayeye naa ti waye.

 
 
Yato si ifi-ami-ye-danilola, orisiirisii orin ati aso oge ni awon amuludun maa n se afihan re nibi iru ayeye bayii. Lara awon olorin pataki ti won korin nibi ayeye Grammy 2014 to waye lana ni toko-taya, Jay-Z ati Beyoncé.
 
Beyoncé lo koko gbe ina oriin kan na pelu awon ara orisiirisii ti n da lori itage ki oko re eni odun merinlelogoji, Jay Z to lo ba nibi to ti n fi orin dabira.
 
Lara ohun ti awon eniyan tun soro ba ni orisii aso ti Beyoncé wo, eleyii to tun je ara oto.( Orisii aso yii nikan ko ni Beyoncé wo, omobirin naa tun paro aso).
 



 

Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

2 comments: