![]() |
Opeyemi Odusanya |
Awon amokun seka kan ti won fura si gẹgẹ bi awon ọmọ ẹlegbẹ okùnk`n ti seku pa omobirin omo ọdun metadinlogun (17) kan to jẹ omo ile iwe Ifafiti Bowen ti oruko re n je Opeyemi Odusanya ni ilu Eko.
Won seku pa Opeyemi latari wi pe won gbero lati ba omobirn naa ni ajọsepo eleyii to ko jale.
Awon ika eniyan yii seku pa Opeyemi ni ile awon obi rọ to wa ni Alakuko ni ilu Eko.
Gege bi iwadii awon agbofinro, won ni osan gangan ni Opeyemi lo ra kaadi ipe eleyii to fe fi si ori foonu re ki awon ika eniyan naa to tele wole nigba ti n pada bo sinu ile lọjọ keta osu keji ọdun taa wa yii..
Opeyemi nikan lo wa ni ile ni akoko yii. Won si ni ko tan ẹ̀rọ amunawa eleyii ti ko ni jẹ ki ariwo ohun Opeyemi goke nigba ti won ba fẹ se ise ibi ọwọ won. Abajade awon olopa ni wi pe won fe fi tipatipa ba omo naa sun ni eleyii ti omo naa lo agidi pelu won. Nitori gbogbo ile lo daru.
Awon okunrin amokunseka naa pada gun Opeyemi lọ́be nikun jalajala ti won si ko gbogbo ifun rẹ sita gèlètè.
Leyin ti won pa omo naa tan, won mu ero foonu rẹ, bakan naa ni won tun mu kọkọrọ moto jeepu baba re to wa lori tabili.
Ori ero foonu yii naa ni awon eniyan ibi yii ti tẹ atejise ranse si iya Opeyemi.
"Igberaga omo re po gan-an, a si ti pa. A ti n so fun wi pe ko fe wa lati ojo yii sugbon o ko jale. Ohun ti oju alaseju n ri, oju re ti ri bayii. A ti pa, a si ti gbe moto jeepu to wa ni ile yin lo.
"Bi o ba fe gba moto re pada, wa si ile itura Lakas tabi Ibudoko Cele to wa ni agbegbe Mile 2. To ba si wu yin e le mu awon olopa leyin, gbogbo yin pata lẹ o fi iku se ifaje."
Inu ibanuje okan nla ni iya omo naa wa, awon to wa nibi isele naa si so wi pe die loku ki ori rẹ daru pelu iru leta ibanuje to gba lojiji.
Gege bi akiyesi awon olopa nigba ti won de ibi isẹlẹ naa, ko si aridaju wi pe awon amokunseka naa pada ri omo naa ba sun gẹgẹ bi ero okan won nitori aso si wa lara omo naa. Awon olopa si ti ri ọ̀bẹ ti won fi seku pa omo naa pelu.
Awon obi omo naa ti ko kúrò nile bayii. Redemption Camp to wa ni oju ona masọsẹ Ibadan si ilu Eko ni a gbo wi pe won wa bayii nibi won ti n so ẹdun okan won fun Olorun Olutunu.
Awon ore Opeyemi ti bere si ni fi awon oro ibanikedun sori ero Facebook Opeyemi bayii.
Okan lara awon ore re ti n je Folake Kuforiji, lo ko oro yii,
"RIP Dear, May your soul rest in perfect peace and may the Almighty God protect and console the rest of your family. A real gem is gone. I remember back then in secondary school when we used to call you Ope International. You left us too soon, but God knows best."
Okan ninu awon oluko re nigba kan ri ti oruko re n je Adeniji Chigozie naa so ero okan re,
"Remember those days in class. You were one of the students I cherished and respected. You were respectful and intelligent. As a teacher, I was very proud of you. The details of the cause of your death are still sketchy and confusing. Nigeria has lost another intelligent and beautiful mind – A great star has fallen!
"Above all, I wish your family and loved ones the fortitude to bear this shocking loss – May God in His gracious nature comfort them, amen!"
Awon eniiyan daju gan sa. won so idile omo naa sinu ibanuje. idajo Olorun maa ke lori won
ReplyDeleteNigba ti a gbo ni ilu Bradford pe odomodebinrin yii ku aanu se wa gaan. Asotele temi ni pe idajo Olorun yoo ke lori awon onise ibi Nigeria. E lo k o sile, laipe ni won yoo waa fi enu ara won jewo ise ibi ti won se. Ara ko le ro won mo ti won yoo fi kuro laye. Won ti se asemo bi Olorun se n be laaye. Okan ninu won yoo para re laipe. Inu inira ni won wa ba yii. Won ko si le ru u la. Bee ni Oluwa awon Omo-ogun wi. A ba eyin obi omode yii kedun gidigi. Oju yin ko nii ribi mo. Olorun yoo tu yin ninu.
ReplyDeleteE seun gan-an.
DeleteAmin. Olorun yoo wa pelu gbogbo wa o
ReplyDelete