Lẹyin ọdun marun-un ti Stewart Richardson ti baye Abdallah Khader ẹni odun meje jẹ raurau nipasẹ ọtin amupara eleyii to sokunfa ijanba ọkọ̀ to sọ ọmọ naa di ẹni ti ko le sọrọ, ti ko le riran ti ko si le rin mo titi ayeraye, iya ọmọ na ti gbera lo si ọgba ẹwon ti odaran naa wa eleyii to wa ni Texas lati lọ salaye inira ti ọmọ naa n la koja ati inu ibanuje ti ebi re wa lati nnkan bi odun marun-un sẹyin.
Iwadii awon olopa ilu Amerika salaye wi pe ina adọkọ duro oju popona ti da ẹbi Abdallah Khader duro sugbon Stewart Richardson ti n wa ọkọ̀ bọ lẹyin won ko duro pẹlu bi o se n sare bọ leyin to ti mu otin yo to si se bẹẹ dabo won lateyin.
Omo odun meji ni Abdallah Khader wa nigba ti ijamba buruku naa sele si.
Gẹgẹ bi ayewo awon dokita alasọ funfun ti ilu Amerika, won ni ida ọgọrin ninu ọgọrun ọpọlọ (80%)
ọmọ naa ti bajẹ raurau eleyii ti ko si atunse si. Bayii, ọmọ naa ko le sọrọ, ko le riran, ko si le rin.
ọmọ naa ti bajẹ raurau eleyii ti ko si atunse si. Bayii, ọmọ naa ko le sọrọ, ko le riran, ko si le rin.

'Ko si ọjọ kan ti mo ji ti mi o ronu nipa ọmọ naa. O ba mi lokan jẹ, mo si kabamo gidi gan-an'- Stewart Richardson
Aworan Abdallah Khader saaju ko to ni Ijamba buruku naa
0 comments:
Post a Comment