Smiley face

Boko Haram Je Odindi Ilu Kan Mole Raurau

Sebi oro awon Boko Haram ko je tuntun mo leti yin. Bi iroyin won se n su yin lati ka, bee gele lo n su mi lati ko jade.

Igba ti opin yoo de ba awon amokunseka gan-an ni ko ye enikeni.

Lojo isegun to koja yii ni awon omo ogun alakatakiti esin Boko Haram yii tun pitu owo won ni ilu kan ti n je
Konduga to wa ni Ipinle Borno.

Awon eniyan bi metalelaadota(53) ni won pa ni ipakupa. Aimoye dukia ni awon eniyan buruku yii dana sun leyin igba ti won pa gbogbo ara ilu tan, koda won tun sun awon ewure ile won pelu.

Ile iwosan kan soso ti mbe ninu ilu naa ni won koko dana sun bakan naa ni won sun Mosalaasi Oluwa pelu.

Gege bi a se gbo, awon omo ogun digboluja ile Naijeria ti won sare debi isele naa tun pada juba ehoro nigba ti won sakiyesi wi pe agbara awon omo Boko Haram naa le ju ti awon lo. Sebi awon agba naa lo wi pe jagunjagun to ba moja ti o mosa ni i bogun lo.

Awon eni ti isele naa soju won salaye wi pe nnkan bi ago merin irole ni awon eniyan ibi naa de loji ninu oko Toyota Hilux bi ogoji pelu aso ologun lorun won ati lawani ti won fi weri-wenu bi lemoomu, ti won si bere si ni fon ota ibon kiri bi agbado yangan.
Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment