Ọmọ ẹgbẹ agbabọọlu Arsenal, Olivier Giroud ti pada tọrọ aforijin lọwọ iyawo rẹ ati ẹgbẹ agbabọọlu rẹ pelu bo se gbe àlé lọ si ile itura nigba to ku bi wakati diẹ lati bọ sori pápá.
Giroud gbe Celia Kay, eni to n se isẹ oge sise lọ si ile itura Four Seasons to wa Canary Wharf ni ọjọ keji osu keji odun yii nigba to ku diẹ ki ẹgbẹ agbaboolu Arsenal wáàkò pẹlu Crystal Palace.
Celia Kay, àlé Olivier Giroud
Olivier Giroud ati iyawo ile re
![]() |
Arsene Wenger
|
Bi ọ tilẹ je wi pe Olivier Giroud kọkọ parọ fun ọga rẹ nipa isele naa. Sugbon bayii ti Camera ti pada tu asiri bi ọmọge se jade niyara ile itura ti Giroud wa ti je ki irọ rẹ ja le lori. Oro taa si ni ki baba mọ gbọ, a se baba naa ni o pada pari rẹ.
![]() |
Celia Kay |
Ninu oro Celia Kay, oni bi wakati bi meji ti oun fi wa pelu Olivier Giroud ninu yara, oni ibalopo kankan ko waye laaarin awon mejeeji.
Kini awon mejeeji wa n se ninu yara ọlọ́yẹ́ fun odindi wakati meji?
0 comments:
Post a Comment