
ALAYE FOTO: Omokekere Ilu South Africa sare wo ori papa leyin ti egbe agbaboolu ilu Brazil fi eyin egbe agbaboolu ti ilu South Africa janle pelu ayo marun-un si odo (5-0). Omo yii sare wo ori papa lati ba Neymar to je omo agbaboolu Bacerlona ya foto. Isesi omo naa wu awon omo egbe agbaboolu Brazil yoku lori won si fi ife han si omo naa nipa bi won se gbe soke gege bi 'Olubori' ni papa isere Soccer City Stadium to wa ni Soweto ni Ojoru to koja yii(5/3/14).
0 comments:
Post a Comment