Awon Yoruba loni moja-mosa laa mo akinkanju loju ogun, jagunjagun to ba moja ti ko mosa ni i ku sogun. Okan lara awon osise Gomina Raji Fasola ti Lagos State Traffic Management Authority ti a mo si LASTMA, ti ko sowo olopa MOPOL alagidi ni agbegbe Ashabi Cole taa ba ya kuro loju ona Lateef Jakande to wa ni Agidingbi ni Ikeja.
MOPOL lagbo wi pe o n se kilokilo fun okunrin LASTMA to fe gbe moto ti won paaki siwaju banki ti Mopol naa n so. Mr LASTMA ni ibi ti moto naa wa ko bojumu rara ati wi pe oun yoo gbe Moto naa lo si tesan awon ni. Moto yii lagbo wi pe o je moto okan lara awon onibara banki naa eleyii ti onibara naa wa ninu banki naa fun idunadura ni akoko isele yii. Oga MOPOL so fun ogbeni LASTMA wi pe ko gboju 'mba', sugbon ogbeni LASTMA ko agidi bori bi faanu Taiwan bi MOPOL se fi idi ibon jan legbe re e 'Oga Ade' ba subu sile yakata. Bi oro se di isu ata yan-anyan-an re e laaarin MOPOL ati oga LASTMA.

0 comments:
Post a Comment