Se awa le tori wi pe Oke Oya ni Boko Haram ti n se Ijamba ka
kawo gbera kani ko si eleyii to kan wa nibe. Yato si aimoye awon alaise ti won n
ku iku ainidi, iyi ati ogo ilu wa tun bo n ja wa sile laaarin awon orile ede
agbaye si i ni. Bi o tile je wi pe oke oya lasan ni isele buruku naa ti n sele,
sugbon to ba je ninu iroyin awon ilu okeere, ile Naijeria ni won daruko fun gbogbo
mutumuwa wi pe Boko Haram ti n se ijamba.
Emi ro wi pe o ti to akoko lati fesun kan Aare Goodluck Jonathan
gege bi igi leyin ogba fun Boko Haram ti n seku pa awon ara ilu nigba gbogbo.
Awon Yoruba naa ni won wi pe ti won ba fi eniyan joye awodi, gbigbe adiye ko ye
ko nira fun iru eni bee rara.
Awon to ba deju sile yoo si rimu wi pe awon olori taani ko kobi
ara si awon isele yii, oju aye lasan ni won se. Oro oselu bi won yoo se pada
sori aga aleefa nigba keji ni gbogbo ilakaka won. Ti Aare ba gba wi pe oun ko
ni onilu ti mbe labe omi ti n lu fun eegun Boko Haram ko jade sita salaye. Ko
salaye fun wa bo se nira fun un lati kapa awon Boko Haram ti ko ba je wi pe oun
gan-an fun ra re lo ran awon Boko Haram nise lati maa seku pa awon ara ilu.
Ibo ni awon Boko Haram ti ri awon ohun elo ija ti won n lo to
lagbara ju ti awon omo ologun Naijeria lo eleyii to n mu awon omo ologun maa sa
seyin loju ija?
Se Aare fe so fun wa wi pe awon omo Boko Haram ni akinkanju
tabi ogbon ori ju awon omo Niger Delta ti Naijeria reyin won lo ni fun wa?
Ti omo Goodluck bawa lara awon omo ile iwe Ipinle Yobe ti wo
pa, se oju to fi n wo oro yii ni yoo maa fi wo?
Oro ti n foju lasan woyii kii se oro kekere nitori ko si eni
to mo ibi ti awon Boko Haram yoo tun doju ija ko leyin awon ilu ti won ti fee parun
tan yii.
Gege bi ara ilu, ani eto. Ara eto wa si ni lati se afihan ero
wa, ati fun awon alase lati teti si ohun ti n beere fun. Gege bi ara ilu, ani
ojuse. Ara ojuse wa ni lati mu idagbasoke ba ilu wa. Bi a ba ko lati beere iru
Naijeria ti a fe, iru Naijeria ti a ko fe ni won yoo maa fi le wa lowo.
Inu mi a dun lati mo nip aero yin. E se.
0 comments:
Post a Comment