Taye gun oko ibeji re to je Kehinde lobe latari wi pe omokunrin naa ko lati ba ni ajosepo ere ife to ladun lojo ti Kehinde o si nile ni Ipinle Delta.
A ko gbo iru eleyii ri, awon Yoruba ni eru la fi n da ba oloro. Kehinde lobi omo tuntun ni Taye ti oruko re n tun je Christiana Otega to je ibeji re e ba lo duro ti lati maa se iranlowo fun un. Gege bi a se gbo, saaju igba ti isele yii sele ni Taye ti feran lati maa woso esubeleke (awon aso ti ko bo ara tan) ni awon igba to fi wa ni ile oko ikeji re to sese bimo. Koda oko Kehinde so fun aya re wi pe ko kilo fun Taye nipa awon aso ti o maa wo wi pe ko dara.
Sugbon lojo ti isele yii sele, Kehinde ti gbe omo re lo si ile iwosan lati lo gba abere ajesara. Taye eni odun merinlelogun (24) ati oko Kehinde nikan lo ku sile. Taye bora si ihoho o si ni ki oko ekeji oun wa to sibe ki Kehinde to o de. Taye dimo oko Kehinde lai wo aso sara ni Jagunlabi ba ko ifoti olooyi fun Taye wi pe iru iwa palapala wo leyii. Oro yii bi Taye ninu lo ba lo si ile idana lo mu obe to si fi gun oko Kehinde ni apa otun.
Awon olopa 'B' Difisan to wa ni Asaba ni Ipinle Delta si ti fi idi oro naa mule fun iwe iroyin LEADERSHIP wi pe otito ni Taye gun oko Kehinde lobe nitori wi pe omokunrin naa ko lati ba 'kiboroki'.
Olayemi Oniroyin, ibeere mi ni wi pe okunrin melo lo le se olooto bi oko Kehinde yii?
0 comments:
Post a Comment