Smiley face

Awon Olopa Ti Mu Amao To N Ko Ibon Fun Awon Ole Ni Ilu Ibadan

Ojo gbogbo ni tole, ojo kan pere ni tolohun gege bi won ti se n so. Owo awon olopa digboluja SARS ti te awon okunrin meji kan, Olatunji Olatubosun ati Abdulazeez Amao, eleyii ti okan je ogbologbo olosa ti ekeji si je igi leyin ogba fun awon ole to je wi pe oun ni i pese ibon fun won.
 
Olatunji Olatubosunni ni owo awon olopa te nibi to ti n digun jale ni agbegbe Ikorodu eleyii to jewo fun awon olopa wi pe owo Abdulazeez Amao ni oun ti n ra awon ibon orisiirisii. Awon olopa wa Abdulazeez Amao lo si inu ile re to wa ni ilu Ibadan won si ba ibon orisiirisii ninu ile re eleyii ti won ni o n  ko wole lati ilu Burkina Faso ati Benin Republi ninu apo elubo.
 

Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment