Orisii arun kan ti kokoro ti oruko re n je Ebola n se okunfa re ti pa awon eniyan bi aadorin (70) ni ilu Guinea, kokoro naa si ti fo wo ilu Liberia bayii.
Ko si ogun fun enikeni ti arun bayii ba n se, iku si ni fun eni to ba se agbako arun naa.
Awon eniyan le ko orisii arun yii nipa eje tabi fifi owo kan eni ti arun naa pa laisi aabo. A si tun gbo wi pe eniyan le ko lara eranko.
Awon ilu ti won sun mo Guinea bi Sierra Leone, Senegal ni won ti tilekun bode won baye lati ma je ki enikeni wole tabi jade si ilu Guinea.
Minisita fun eto ilera ilu Liberia, Walter Gwenigale se alaye wi pe arun naa wole si ilu Liberia latari omobirin ilu naa to lo fe won ni ilu Guinea eleyii to pada wale pelu arun naa to si ko ran aburo re kan eleyii ti awon mejeeji ti ku bayii.
Enikeni ti iru arun yii ba ti mu, eje ni yoo maa da lara eni bee, eje naa ko si ni duro titi yoo fi koja si orun alakeji.
Home / Uncategories / Kokoro Ebola To Buru Ju HIV Lo Ti De Ile Aye: Awon Eniyan Bi Aadorin Ti Ku Ni Afirika
Subscribe to:
Post Comments
(
Atom
)
0 comments:
Post a Comment