Smiley face

"Igba Eda, Asiko Eda Wa Lowo Baba Oke" -Iyanlaya Oko Tuntun Davido

Dafiidi omo Adeleke ti opolopo awon eniyan mo si Omo Baba Olowo tun ti ja oko tuntun 2014 Mercedes Benz S63 AMG eleyii ti owo re yoo to nnkan bi ogun milionu owo naira(20M) ile wa.

Joojumo ni Davido n ra moto, awon oko tuntun bi marun-un lo faso bo mole lagbala ti ko si eni ti n gun won. Eleyii ko si da duro lati maa ra oko tuntun to ba gori ate.

Ilu Atlanta Georgia ni won bi David Adedeji Adeleke si ni odun 1992.

O ti bere eko nipa imo Isakoso Okoowo Sise ti a mo si Business Administration ni Oakwood University ko to pada wa si Babcock University to wa ni Ipinle Ogun.

Oluko ile iwe giga ni Omowe Vero Adeleke to je iya re ko to di wi pe iya rebi agba n re. Ero iya re si ni lati ri Dafiidi gege bi onimo nla lawujo awon onise alakada. Sugbon orin ti n ja lori Davido ko je ko sinmi.

Davido n mura lati lo si ilu South Africa lodun yii, nibi ami eye MTV Africa Award 2014. Oun kan naa lo si je omo Naijeria to foju han julo ninu awon isori ti won pin ami eye naa si. Iroyin naa wa [NIBI]


Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment