Owo awon omo ologun Nigeria tun ti te awon omo Boko Haram ti won fi joojumo se ise ibi. Awon ti owo te yii ni won ti bere si ni jewo wi pe awon ni irumole ti n dun sise ibi ni awon ilu bi Nasarawa, Taraba ati Zamfara. Ninu atejade adari iroyin to je mo aabo ilu, Major General Chris Olukolade ni won ti fidi iroyin isele naa mule se.
Gege bi iwadii Oniroyin, awon ti owo te yii lale se apejuwe won gege bi ojewewe iko Boko Haram, eleyii to je wi pe awon ise ibi keekeke ni won gbe fun won lati se tabi ka pe won loju tuntun ti won n ko ise buruku lowo.
Ju gbogbo re lo, Yoruba ni ati kekere lati n peka iroko, to ba dagba tan ni doosa ajiki. Awon ologun ti bere si ni fiya je won lati gbo ekunrere alaye nipa awon oga won.
Olayemi Oniroyin, orisii gege (pen) oto ni mo fi n ko iroyin Boko Haram. Nitori mo gbagbo wi pe bopeboya Boko Haram yoo di awati, gege (pen) mi yoo si di apati segbe kan.
Eni ojo to dara!
Subscribe to:
Post Comments
(
Atom
)
0 comments:
Post a Comment