Mo ranti Olaitan Olanipekun.
Igba nla tofo ko roke omi mo.
Akeregbe tofo ko roke odo gun.
Awo funfun oba tofo ti di panti ti won da sakitan.
Odun kerin re e t'omo Olanipekun ti lo lai dagbere.
Gbogbo aye pe Baracko Grin ko je mo. Won pe 'Lyrical were' bi ko tati were.
Oosa orin o dahun,
Olori awon Omo Ita sun bee ni o ji mo.
Sebi won ni tawo ba ku, awo ni i sedaro leyin awo.
Ede ara to pe ti o tan lo jomiloju.
Ise orin to yii bi awo erin lo je n si fila funse opolo.
Oju lo n kan mojesin ti i rorun.
Sebi bo ba dagba-dogbo iku naa ni.
Kembe ti gbona lehin tutu ninu.
Daro-daro ti ku aso aro o si mo.
Peja-peja loku laye o reja jeba tutu.
Dagrin lo, ojulowo orin abinibi lo.
Apede bi eni n mura ijakadi.
Akinkanju, asingbere orin bi eni sawo.
Soro-dorin sorin-doro bi eni pofo.
Joojumo nise awo nile alara
Joojumo ni won gbebo nife Ooye
Joojumo lawa yoo ma se iranti akoni.
Baracko Grin, Ó digba!
Subscribe to:
Post Comments
(
Atom
)
0 comments:
Post a Comment