Smiley face

"Ti Mo Ba Ranti Bi Alya Se Di Mo Mi Nigba To Gbo Wi Pe Mo Setan Lati Fi Kidinrin Mi Sile, Omi Maa N Jade Loju Mi Ni" -Oluko To Gba Akekoo Lowo Iku Ojiji

Awon Yoruba ni ajumobi ko kan taanu, eni ori ran si ni ni i seni loore. Alya Ahmed Ali omobirin eni odun metala (13) lo ni isoro kidinrin eleyii to je wi pe ise abe nipa pasipaaro kidinrin lo le gba emi re la lowo iku to n seju si i.


Iya re yoju si oluko Alya wi pe omo oun ko ni lanfaani lati wa si ile iwe fun awon akoko die latari isoro to ni.

Ray Coe eni odun metalelaadota (53) ni oluko Alya, aanu omo naa si se gidi gan-an pelu alaye ti iya omo naa se fun un.

E gbo ohun ti Ray so pada si iya omo naa ati ero re nipa igbese to gbe lori Alya to je akekoo re :


'I said "Can I put my name down as a donor?" I knew what being a donor meant and I knew there was a possibility it could go ahead and I
knew the implications. I knew exactly what I was doing.

'There is a verse in the bible that says something like: "Maybe you were born for such a time as this". It just clicked and I knew then that it was right.


'When we told Alya, she just gave me a big squeeze and her face lit up. It brings tears to my eyes whenever I think of that.'

Onigbagbo ni Ray nigba ti Alya ati idile re je Musulumi ododo, omokunrin naa ko wo tesin rara lati se ohun ti okan re wi pe ko se fun omo naa.


Awon dokita se ayewo Ray, won ni kidinrin re ba ti Alya mu ati wi pe o le fi kidinrin sile fun omo naa.

Ise abe yii waye ninu osu keji odun yii ni London's Great Ormond Street Hospital, ohun gbogbo si lo gege bo ti ye ko lo.

Alya ati oluko re si wa ni ile iwosan nibi ti won ti n gba itoju titi di akoko yii, a si lero wi pe laipe won ko ni pe jade.


Ray tun so nipa ero awon obi omo naa nipa ohun to se fun omo won:


'For her parents, it's not words that
can express their gratitude. For them, I have saved their daughter's life.

'It's like I am another family member now.'

Ahmed Ali eni odun metadinlaadota 47 to je baba Alya soro nipa oluko omo re.

'Ray has given Alya much more than just the gift of life. He's an amazing man, we owe him so much.'

Olori ile iwe Alya to je oga fun Ray, Wendy Bowe ko le pa ero re mora nipa okunrin ti gbogbo eniyan ti bere si ni se apejuwe re gege bi 'olurapada-emi'.

E gbo ohun ti Ogbeni Wendy Bower so:

'Mr Ray Coe has gone above and beyond the call of duty with this selfless and noble act.

'He is a very humble and modest man. The whole staff are in admiration for his kindness. He has
given a new life to Alya and her whole family.'

Olayemi Oniroyin, ohun ti mo mo nipa aye yii ko po rara. Sugbon lara ohun to dami loju ni wi pe ohun gbogbo maa tan lojo kan. Ogbon maa tan, imo maa poora, laakaye maa fo lo bi eye, igba kan si n bo to je wi pe owo ati ola pelu okiki ko ni niyi mo.

Sugbon ohun ti yoo seku titi lailai ni iwa ti a wu sile ka to lo, ilakaka wa lati mu igbe aye rorun fun iran omoniyan.
Bi a se lo oore ofe ti Edumare fun wa ni ile aye. Awon nnkan won yii ni yoo wa titi lailai.

Stratford to wa ni ila oorun ilu London ni Alya ati awon obi n gbe. Ki Edumare ba wa da alaafia pada si ara awon mejeeji ni kiakia. Amin.

Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

1 comments:

  1. Lesson to be learnt by so many people.. Ati musulumi pelu kristieni.. Hummmmm! Ife ni akoja ofin..

    ReplyDelete