Smiley face

E Wa Wo Awon Omo Boko Haram Ti Won Ju Ado Oloro Si Nyanya Ni Ilu Abuja

Awon Yoruba ni bi iro ba lo logun odun, ojo kan soso ni otito yoo sare le ba. Owo awon osise alaabo SSS ti ijoba ti te awon omo Boko Haram marun-un ti won ju ado oloro to bu ni Nyanya lojo kerinla osu kerin odun yii (14/4/14) nibi ti aimoye emi ti sofo danu.



Oruko awon marun-un ti won gbamu naa ni Ahmad Rufai Abubakar, Muhammadu Sani, Ishaq Adamu, Yusuf Yau Saidu ati Anas Isah gbogbo won si ti jewo wi pe lotito ni awon jebi esun naa nigba ti won se afihan won fun awon oniroyin lonii (12/5/14) ni ilu Abuja.

Won ti ni ile ejo ni won yoo ko won lo bayii nibi won yoo ti dajo won botito ati botiye labe ofin orileede Naijeria.

Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment