Smiley face

[Foto] 'Walahi! Mo Ta Lenu Yeriyeri' - Ini Edo

Ti ija ba wa nibe, e ja e pari e, Omo eni ko ni sedi bi okoto ka wa ko ileke sidi omo sombodi lailai. 

Omo yii rewa pupo! 

O da bi eni wi pe ki maa la bi oyin. Oju re mo fefe bi iwaju pepe Oluwa ni soosi, irun ori re lale kedere bi osumare, igo oju re duro rekete bi eni wi pe won bi moo ni, ipenpeju re n pese bi soja Idumata bee naa ni ete re n soro lai yanu.  Eyin oju re n fi awon koodu to lagba ranse bi igba eniyan lo bluetooth lori foonu. Toro ereke re iyanu ni. Atike oju re, wahala. Bi eniyan fi omo we omo,  afaimo ki onitoun ma loku eniyan lorun.


Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

3 comments: