Smiley face

Awon Omo Akin Fi Owo Lasan Gba Ibon Lowo Ole

Won ti setan bayii lati fun awon omokunrin meji kan ni ami-eye akinkanju pelu bi won se woya ijakadi pelu okunrin odaran olosa kan eleyii to mu ibon dani lati ja ile itaja ounje igbalode ti a mo si McDonalds lole ni ilu Australia.


Omo ilu Sir Lanka ni Kasun Fernando ati  Ishan Chathuranga, iwe ni won si wa ka ni ilu Australia.

Bi o tile je wi pe gbogbo eniyan n yin won fun akinkanju ise ti won se, sibesibe awon omo yii n beru ki awon obi won ma gbo nipa ohun ti won se ni ilu won lo un.

"At first mum was a bit scared, but she's really proud now," oro Kasun pelu awon oniroyin.
McDonalds to wa ni Mulgrave ni isele yii ti sele, e gbo ohun ti Kasun so.

"When I saw the gun was away from him and he was busy collecting the money, I thought I can
take him on, so I jumped on him and put him down. "
 
Nibi ti Kasun ti gbe igbese akin ni ore re naa ti ran lowo pelu bi won se ki ole naa mole titi awon olopa fi de ba won  nibe.


Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment