Smiley face

Ise Iyanu Ti N Sele Ni Soosi Wa Ki Se Seresere o" - T.B Joshua

Lati igba ti ile igbalejo ijo Sinagoogu ti dawo ni ilu Eko, eleyii to seku pa awon eniyan ti won le logorun, awon oniroyin kan ni ilu South Africa ti bere si ni fesun kan Ojise Olorun Oga Ogo, Wooli Onise Iyanu, Temitope Balogun Joshua gege bi Pasito ti ise iyanu re ko dajusaka.

Oniroyin kan ti n je Jacques Pauw lati ilu South Africa lo gbe iroyin naa jade.

Sugbon Pasito T.B Joshua ni, "Eyin eniyan, e ma ma da awon oniroyin yen lohun o.

O seese wi pe awon eniyan ti won dana ijamba ti ile igbalejo ijo wa fi wo ni won tun wa nidi awon iroyin eleje ti won fon kiri bi igba ti eniyan fon agbado sile f'adiye.

Orijina ponbele ni awon miraku wa. Se bi laifu ni gbogbo wa maa n wo lori telifisan ijo na. Awo kan ko si lawo ewa rara."
Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment