Bi igba ti iku n le Baba Wande inu fiimu Toluwa Nile ni gbogbo awon oloselu Ipinle Ekiti se n sa kijokijo kiri lati igba ti awon agbegbon kan ti rojo ibon fun olori egbe awako Ipinle Ekiti nigba kan ri, Omolafe Aderiye ti won seku pa l'Ojobo to koja yii.
Aderiye lagbo wi pe o je okan lara awon igi nla ti won wa leyin Ogbeni Ayodele Fayose to je Gomina ti won sese dibo yan ni Ipinle naa.
Eru ti n ba gbogbo won ni wi pe ko si eni to mo eni ti iku kan lori ila. Iku ti n pa ojugba eni, owe nla ni i pa fun ni. Ki oro naa ma lo dabi omugo eko meji ti won n je okan lowo ti ikeji duro tandi bi soja idumata lai mira. Idi ni yii ti gbogbo won fi na papa bora. Koju ma ribi gbogbo ara loogun e.
Nibayii, Gomina Fayemi ti Ipinle naa ti kede ko-nile-o-gbele lati ago meje ale si ago meje aaro lojoojumo titi di igba ti alaafia yoo fi joba.
Subscribe to:
Post Comments
(
Atom
)
0 comments:
Post a Comment