Ogbon nla pagbo yimika,
Olayemi mo setan mo fe fon bi erin lakatabu.
Aditu ede n gbemi lokan mo setan mo fe korin ewi atata.
Beeyan ko ba joju Olayemi Oba kii kewi fun.
Mo koja akotobanu ninu ise opolo.
Emi yato somode akewi ti n kalolo oro.
Bi agogo mi ba wa n dun kango-kango,
Tori Taye-Kehinde omo Olajire le mi se n pede ara.
To ba je torin gidi to gbamuse, asiko ti to ti mo fe tuso loju oniro.
To ba je torin iyin ti n gbeni soke niwaju Oluwa, awon omo Olajire gbayi pupo.
O wu Edumare lo se ori ewa fakuko.
Okin loba eye, ise Oluwa ni.
Ajanaku tobi sugbon Edumare lo gbade fun kinihun ololaaju.
Ibeji Olajire se ojo ibi lojo kefa osu kesan-an odun
Olayemi korin gidi inu awa dun.
Emi j'ewa ibeji mo tun jaadun.
Ibi mo ti n jamala gbigbona ni mo ti n laagun.
Adura mi ni Ire owo, ire omo atemi gigun.
Amin.

0 comments:
Post a Comment