 |
Bob Marley |
Ale ana ki i n to sun, orin Bob Marley ni mo n gbo. Opolopo awon orin Bob Marley lo kun fun ogbon ati ijinle ede. Odun 1945 ni won bi Robert Nesta Marley ti gbogbo eniyan mo si Bob Marley ni Saint Ann to wa ni ilu Jamaica. Igba to pe omo odun merindinlogoji (36), ni odun 1981 lo gba ilu Amerika de ajule orun. Bi Bob Marley ko tile si laye mo, okiki awon orin to ti ko ko je ki oruko re pare.
Die lara ohun ti Bob Marley wi ninu awon orin re ni yii:
"You can fool some people sometimes, you can't fool all the people all the time."
"O le mu opo awon eniyan lobo fun awon igba kan, o ko le mu gbogbo eniyan lobo ni gbogbo igba."
Bi eniyan ba le were titi ti were oun
sare lo lai boju weyin, ti were ba de bi ti ona ti pin dandan ni ko yiju pada.
Bi ilu Nigeria se ni ola to, ti eniyan kookan ni orileede Nigeria ba ni oko
ayokele meta lagbala ko ti i poju. Sibesibe awon eniyan ko beere oko ayokele,
aadota (50) naira ti won oo fi woko ni ko si lowo elomii. Owo iresi ogorun
naira (100), ewa aadota (50) naira, ounje osan-an lai seran, ati piowota omi inu
ora oni naira marun-un (N5) ni omo ogbon odun (30yrs) wa ti o fi jeun ti ko si
lapo re. Agba to ji ti ko ba ooko ji, o ti ku won o ti gbe sin ni.
 |
Awon odo ti won wa ise Nigeria Immigration Service |
Awon eniyan ko beere oun to po rara,
won ko tile gbero ati ko ile alarinrin bi eyi ti nbe ni Gwarimpa, Lekki tabi eyi
ti won ko si Bodija n’Ibadan. Ohun ti won fe ni ibi ti won oo maa gbe ori won le
to ba di lasaale.
Ori ti n fo awon odo ile yii, ohun to fa ori fifo ko si ye
mi. Boya nipa iroyin owo bilionu aimoye ti n poora lojoojumo ti won n gbo seti
tabi ise ti won ko rise ti won n wa kiri ti kosi nibi kankan lo fa efori tuulu. Sugbon
ori n fo won gidi gan-an, owo iya won ni won si ti lo n gba owo fensiiki ti won
lo lati dekun ori fifo abaadi. Sibesibe ori fifo o lo.
 |
Se Baba Ijebu Ni Ireti Awon Mekunnu Bayii? |
 |
Ise Asewo Ti Di Gbajugbaja |
Ko si eni rere nibikibi. Yemi
Elebuubon ti ni ‘Eeyan won, araye eniyan soro’. Eni afeyinti bi o ba ye wiwiniiwi.
Eni a gboju okun le ko si jeni agba. Igi taa ba feyinti ka maa je igbadun, gbogbo
ara lo fi segun. Eni o ye ko feni loju ti fata senu. Sebi igi taa tori re
jiya, o ye ko le dana fun ni ya. Gbogbo awon olori wa pata ni odale, asise nla
gbaa ni ominira taa gba lowo ijoba Biritiko je.
 |
Ko ba dara ju ki ile Nigeria si wa labe ijoba Biritiko bi ilu Scotland. |
Kini anfaani ominira ti ara tun ni
gbogbo mekunnu? Kini anfaani orogbo na? A pa ko lawe, a fi senu o tun koro bi jogbo. A
tun ni ka figi re dana, won ni eewo ni enikan ki i figi orogbo dana. Orisa boo le
gbemi fimi le bi mo ti wa. Bi ebiti ko ba peku o ye o le feyin feleyin. Bi
eniyan ko si le jawe lori asewele a ki i ko tori re kuro.
 |
Bintin lara opolopo ijamba Boko Haram |
 |
Ijoba ko lati san owo osu ajemolu awon oluko |
 |
Rogbodiyan owon gogo epo robi |
 |
Ohun kan soso to se pataki ju lo... |
Awon oba alaye ati ijoye ilu to ye ki
won maa gba eto ilu lowo awon ijoba fun ara ilu ni won ti tori ijekuje so
ori ade di yeyenatu. Enu to ba ti je dodo ko ni le sododo. Agbalagba to ba si
so agbado modi, dandan ni ko di alawada adie. Agba ti o farabale ni i fara gbegba.
Mo nife orileede mi pupo gan-an, teni-n-teni, takisa n taatan. Omo eni ko ni sedi bebere ka wa fi ileke sidi omo
elomii laelae. Ibi ori dani si laagbe. Sugbon odaju, eniibi, ika, ole, jaguda,
gbewiri, olosa, barao, tiifu, wobia, alanikanjopon, onijekuje, ajeun-omo-nu-oyun,
oloorun, onidoti, obun, olodo, akurari, olopo dudu, keferi alainiberu Olorun, apaayan ni
gbogbo awon olori wa pata.
 |
Ta lo pa Bola Ige, Dipo Dina ati Funsho Williams? |
E je ka yopin loju ka fihan oju. E wo ni ki omo maa
jale ka maa lomo n fewo. Baa wi aa ku, baa si wi orun la n lo. Baa sooto ba o
sooto, o di dandan ki eye oko o fo lo.
 |
Oro po ninu iwe kobo |
Ojo ti mo gbo itan Tunde Fasasi (oruko
re gidi ko ni yii), mo dupe lowo Olorun. Ti oloju kan ba ri eni ti o loju rara
yoo sope fun Oluwa oba. Itan aroso ko, Isele to sele gidi ni. Odun karun-un
re e ti Tunde ti n wase leyin to jade ile iwe. Igba ti o rise se lo lo ra aga
ati tabili segbe titi lati maa fi se ise teliwaya.
 |
Ijekuje awon olori wa lo je ki awon ile ise ibanisoro maa re wa je pelu owo goboi ti won gba lowo ara ilu. |
O n ta kaadi ipe, eni to ba
fe se eloelo ni gba muri kookan (N20) lowo won fun iseju kan ti won ba lo lori
ila. Owo pensan baba Tunde ni won to papo mo owo ti iya Tunde ba pa nibi worobo
ti fi n saje. Ireti won ni wi pe ti won ba fori ti titi, ti Tunde ba jade iwe yoo
le ran aburo re lowo. Sebi ti okete ba dagba tan, omu omo re ni i mu. Ati wi pe tita riro laa kola, to ba
jina ni i doge. Adun ni i gbeyin ewuro. Leyin okunkun birimu, imole lo kan.
Sugbon riro ni teniyan, sise ni t'Oluwa oba. Se awa le so wi pe Oluwa oba ni ko
je ki Tunde rise se, rara o.
 |
Awon osise feyinti n to lati gba eto won lowo ijoba |
Amukun eru re wo, oni oke le n wo e o wole. Baba
Tunde saisan, awon ijoba o sanwo pensan kia, lojo kan ni Ogbeni Olarewaju Gbadamosi
dake ti ko si ji mo. Ibi kan ni aburo Tunde obirin n gbe l'Abuja, won
ni kojo omo odo tabi kabani sise ile ni i se nibi to wa loke oya. Ki i se wi pe
o wu bee. Bi o ba r'adan, eniyan le fi oobe sebo.
 |
Arokan ni i fa ekun asun-un da... |
Ko saa ma fi joko sile lasan ni.
Iya o jeun, baba o jeun, won o tun sanwo ile. Bi eniyan ba n sare ki oju ma tini,
ti oju ba ti tini are ka maa ku lo kan. Iduro o si, ibeere o si feni to gbodo
mi. Igba to gbo iku baba re ni Morenike fi n pada bo nile. Se e mo awon olopa alaso
dudu ti won maa tewo gba muri kookan ni masose? Awon ni won da oko ti Morenike wa
ninu re duro. Awako ni i ba won lagidi ni won ni olopa ba yinbon. Olorun nikan lo
ye bi ota ibon naa serin to fi ba Morenika lapa. Morenike o ku sugbon apa naa
ko wulo fun-un mo.
 |
Ki lo fe je ojo ola awon wonyii? |
Ko le pada si oke oya mo, joojumo ni won si n lo si osibitu lo
gbatoju. Joojumo ni apa naa n ro Morenike. Awon kan tile ni boya aye ti toju bo
egbo apa re ni ti ko fi jina lati ojo ti won ti n toju re. Oko iya Tunde ti ku,
ise iya Tunde si ti doloogbe lowo bukata repete, joojumo ni Morenike n jerora.
Gbogbo ebi lo ti salo fun won tori bukata. Kaluku lo kun un ru tie kiri. Temi
gan-an tomi leru, e ma di kun-un. Oju titi ni Tunde si wa nibi to ti n gba
muri kookan lowo eni ba fe se eloelo. Owo ti Tunde n pa ko to o jeun ka to wa
so ebi to fi sile.
 |
Gomina Ipinle Abia nigba kan ri, Orji Uzor Kalu n gbadun ola re leyin odun mejo ni ile ijo |
 |
Opolopo ile ati dukia ni Kalu ni nilu South Africa ati London |
 |
Kalu Oba Onile Funfun |
 |
Bi eniyan tile soogun owo ko le ni owo bi Kalu. |
Mo mo omo gomina to ti je nigba kan
ri to je wi pe gbogbo opin ose ni maa gbe baalu lo silu London lati lo wo boolu Premiasiipu ilu Oba, aa si pada wale lojo Aje. Ti o ba n lo, obirin meji ni i ko dani
pelu awon ore re bi meta. Bakan naa ni mo ti ri aburo gomina kan ri to so wi pe
oun o fi owo baye asobode ile itura kan je niseju mi korokoro nigba ti asobode
naa so fun wi pe won kii to sibi ti n to si (aburo gomina naa ti mu oti yo
nigba naa). Esi ti aburo gomina naa fun ni wi pe, “ maa fi owo ba ti e je”. E
dakun, kilagbe ki le ju?
 |
Baba subu nibi ti o ti fe gba owo pensan |
Bakan naa, mo ni ore kan to ti ni
anfaani lati lo si awon ilu okeere bi meta tabi ju bee lo. Omo eniyan pataki ni. Awon
Yoruba sibo, won ni ola abata ni i modo san, ola baba omo ni i mu omo yan fanda.
Ore mi yi ti ni anfaani lati wo inu ile ijoba apapo l’Abuja - Aso Rock naa ri. Ojo kan lo so
iriri re fun mi. O ni iru aye ti won je ninu ile ijoba apapo to wa l’Abuja, o
ni oun ko ri iru aye bee nibikibi ni gbogbo ilu okeere ti oun ti de ri. O
salaye die fun mi, emi gan-an yanu ni. Eni i sise wa ninu oorun, eni gbowo wa
nibooji.
E je ki n tun pada sori oro Bob Marley Akoni igbaani,
"You can fool some people sometimes, you can't fool all the people all the time."
"O le mu opo awon eniyan lobo fun awon igba kan, o ko le mu gbogbo eniyan lobo ni gbogbo igba."
 |
Iyawo dun losingin.... |
Aifoonu eleyii ti won fi asan goolu gidi se n won ha ni saara lojo ti omo Aare n se igbeyawo alarinrin fun gbogbo alejo. Ilu Okeere bi meta ni oko ati iyawo tun fo de nikete ti ayeye igbeyawo won kase nile lati lo se onimuunu pelu opolopo owo dollar. Aimoye omo mekunnu ni won n ku lojoojumo loke oya, nigba ti awon kan tile sonu ti a ko ri won mo.
 |
Owo aifoonu eyokan to bere okoowo fun elomii |
 |
Awon wo ni obayeje gan-an ? |
Akosile die ninu opolopo awon owo ti won ti ji ko pamo si ilu okeere nigba kan tele ni yii. Sampu lasan ni mo fi eyi se, eyi ti won ko pamo loteyii tun goboi. Se e ranti $9.3M ti won ri ni South Africa. Sebi eyi ti asiri tu lagbo, aimoye taa gbo nko?
 |
Awon Oludibo Ni ipinle Osun |
Omo Aare to se igbeyawo ni yii saaju ko to lo si ile oko. Aimoye moto ni fi n se faaji, o si feran ko maa ko oruko inagije re si awon oko re gbogbo gege bi nomba. Awon kan tile so wi pe kii se omo bibi inu re gan-an wi pe o gbato lo wa so domo.
 |
Omo Aare: Elizabeth omo jayejaye |
 |
Elizabeth |
Iya n je opolopo awon eniyan o, eni
ba ri ounje ojumo je ko dupe lowo Oluwa. Eniyan to wa ni alaafia ko mo ohun ti
oju awon eniyan to wa ni osibitu n ri. Awon osibitu wa ko yato si ile iku, eni
ori ba koyo ni i pada wale ti won ba lo. To ba je iro ni mo pa, kilode ti awon
olori wa ki i se lo sibe (awon oba gan-an kii ya be).
Awon olopolo dudu ko ni won
se yahoo-yahoo o, boya ti won ba ri ohun gidi fi opolo won se boya won ko ba
jawo ninu ise ibi. Kosi omo ti o mowe, okun inu la fi n gbe tode. Ti omobirin ba ji ti n fidi re se
sadaka kiri, e je ka ronu ka to fun iru obi omo bee lepe. Se ise asewo je ise
ti eniyan mu yangan ni? Opo alagbara lo ti dole (laziness). Opolopo ologbon ni
won ti domugo. Aimoye oku ni won rin ni titi bi alaaye sugbon oku ni won.
Mo nireti wi pe Nigeria yoo dun lojo
kan. Mo si gbagbo wi pe abiku yoo di abiye. Sugbon e ba mi jise Bob Marley
fun won. E so dorin titi yoo fi ko si won leti:
"You can fool some people sometimes, you can't fool all the people all the time."
"O le mu opo awon eniyan lobo fun awon igba kan, o ko le mu gbogbo eniyan lobo ni gbogbo igba."
Olayemi Olatilewa ni oruko mi. Mo si
feran orileede mi bi emi mi. Idi Pataki ti mo fi wa ni lati wa ki yin ku odun ominira. Mo ro yin ki e mu okan le gidi pelu igbagbo to
jinle. O ni le koro, sugbon adun ni i gbeyin ewuro. Leyin okunkun imole nbo. Bi
ekun pe dale ayo n bo lowuro. Kosi ohun to le ti kii ro. O di gba kan na!
Apero lori NAIRALAND
Apero lori YORUBA DUN
0 comments:
Post a Comment