Eniyan le ku ko tun pada ji.
Sebi alagbara ni Olorun Ubangiji?
E ma dan agbara Olorun wo ko seeji.
Okunkun laye oro Oluwa ni imole.
Odaju laye won ko yato si paramole.
Ireti mi wa ninu agbara Olorun mi.
Alaseloluwa to da erupe ati omi.
Oro Re ni eni to ba fi omije furugbin.
Dandan ayo ni o fi ko ere ohun to ba gbin.
Gbogbo ogbon lati da ko si eyi to je.
Odoodun ni awon ika eniyan tuwa je.
Ninu ero won tun ni lati pawa je.
Idi ni yii ti mo fi sa too wa Olorun Erujeje
Igbagbo mi tobi adura mi ni ko po.
Bi o tile je wi pe iye awon ti n kepe O po.
Baba mimo fi aanu gbo adura temi.
Saanu fun Naijeria orileede mi.
Mu iponju ati wahala kuro ni ile wa.
So Nigeria di ilu ogo ati ewa.
Olorun mi gbo adura mi.
Mo ke pe O ma doju adura ti mi.
Fi ara ni awon ti won daamu ilu mi.
Pa won run bi Sodoomu ati Gomora.
Fiya je awon ota ki won poora.
Olorun mi Ominira ti E la wa n fe.
Mo toro aforijin fun awon ese ti a ti se.
Ilakaka awon akoni wa ko gbodo ja sasan.
Alagbara dide ko o gbesan.
Olorun Mi dide ko Gbo Adura Mi. Amin
Subscribe to:
Post Comments
(
Atom
)
0 comments:
Post a Comment