Smiley face

Asiri Ọọni Ile Ifẹ Ti Tu: Kini Ọọni Se Fun Jonathan?

Awon Yoruba ni ohun to ba jọhun la fi n wehun. Sebi eepo ẹpa lo jọ poosi ẹliri. Eniyan to fi ori ologinni se apejuwe ori amotekun ko se 'misiteeki' rara.

Kunle Ologundudu mbe loke okun, ogboju akewi ti mbe niyewu salaye ohun to ruju nigbagede ni i se. Bi Olanrewaju Adepoju ba so otito oro tan, aya won kii ja. Awon Akewi mejeeji yii ni won fidi oro naa mule nigba rogbodiyan June 12 to waye lodun 1993 wi pe Oba Okunade Sijuwade ti mu Ibrahim Babangida lo sojubo Oduduwa lati lo re e bori fun un.

Won ni eyi wa lara ohun to mu iran Yoruba jeya naa gbe; ti Babaginda si mu awon iwa ika ọwọ rẹ jẹ gbe.

Ina ti won ba daalẹ de ẹyẹ gunnugun, ẹyẹ mii ni won fi n sunjẹ. Taaba la o moni, ola laa mu. Enu-enu lẹsẹ fi n pa ekurọ oju ọna. Enikan o lẹyẹ mu, iyẹ lasan ni won o maa wo leyin ẹyẹ Gbadamọsi. Ibrahim Gbadamosi mbe ni Minna doni nibi o gbe n tẹlẹ jẹẹjẹ bi oba alade.

Won gbe poosi Babangida ni Ijebu-Ode ati lawon ilu mii ni ile karo-o-jiire, nigba ti awon kan wọ asọ odi lọ sọja lati gbe IBB sepe gbigbona. Awon Abiamo kan tilẹ rin ihoho wọja lati fi okunrin naa gegun sugbon ofo ni gbogbo rẹ jasi.

Awon àgbà ti oro ye so wi pe ojubọ Oduduwa to wa ni ile Ife ti won mu IBB wọ nigba naa ni fi jẹ ki gbogbo ohun ti awon eniyan se fun-un ran. Sebi ti ina ko ba lawo kii goke odo. Eegun ti n jo lori omi ni, onilu re wa nisale odo.

Aimoye awon oniwe iroyin naa ni won si jeri wi pe oseese lotito ki Ooni se ohun to se.

Ni ojo kinni osu keji odun 2003, Ooni fi Atiku Abubakar je Adimula ile ife. Opolopo awon omo Oduduwa ni inu won ko dun pelu bi Ooni se ta ogún omo Yoruba fun omo gambari. Won ni iru oye pataki bee ko ye ko bo sowo eni ti kii se omo Yoruba rara, nitori oye pataki lo je laaarin iran Yoruba.

Koda, Bisi Akande to je gomina Ipinle Osun nigba naa kọ lati yoju sibi ayeye iwuye naa to waye ni Ile Ife.

Awon eniyan ni owo tabua ni Turaki ti Adamawa to je igbakeji Aare Naijeria nigba naa fi ra oye naa lowo Ooni.

Jije oye nla naa ni ile Yoruba wa lara ilakaka Atiku lati ra iyi fun ra rẹ niwaju awon omo Yoruba, nitori awon akoko yii ni ọkọ Titilayo bẹrẹ si ni gbero ati di Aare ile Nigeria.

Nibayii, ohun kan ti a tun gbo ni wi pe Oba to wa ni ipo keta ninu awon oba to lowo julo ni ile Afirika, Oba Okunade Sijuwade ti  Ile-Ife ti mu Aare Goodluck Jonathan wọ ojubọ Oduduwa Atewonro. Gege bi awon ti oro naa lu si lọwọ se sọ. Won ni yoo fe to igba marun-un otooto ti Aare Goodluck n yo wa si ile ife, to si n se ipade idakọnkọ pelu ori ade.

Yato si obitibiti owo dollar ti Goodluck fi sakasaka gbe wole, a tun gbo wi pe Aare ti se ileri lati da ipinle tuntun mii kale lati inu Ipinle Osun eleyii ti yoo maa je Ipinle Oduduwa nigba ti ile Ife yoo si je olu-ilu fun Ipinle naa.

Iru ise agbara wo ni Ooni se fun Aare Goodluck Jonathan lojubo Oduduwa?

Se agbara isura ni tabi agbara lati bori ninu eto idibo to mbo lọjọ kejidinlogbọn osu keta odun 2015?

Ibeere yii je ohun ti a ko ri enikeni dahun re titi di akoko yii.

Ilu Ososa lẹgbe Ijebu-Ode ni won bi Hubert Ogunde si ni ojo kokanlelogbon osu karun-un odun 1916. Igba to pe eni odun metalelaadorin (73) lo dubule aisan si ile iwosan Cromwell to wa ni ilu London. Ile iwosan naa lo si ku si ni ojo kerin osu kerin odun 1990.

Opolopo awon eniyan ni won gba wi pe ogbologbo awo ni Osẹtura jẹ nigba aye rẹ. Sugbon emi gba wi pe onise ọlọpọlọ haun nii se. Onise ọlọpọlọ ti imisi re n ba ni leru bi eni orisa n ba sọrọ.

Die lara orin baba naa ni yii:

"Otito ni yoo leke laye
 Otito ni yoo leke lorun
 Otito ni yoo gbe wa o goke agba."

Maa duro nibi ni temi. Sebi o tan lenu lasan ni, oro si ku nikun.

E le tele mi lori twitter fun awon iroyin oju-ẹsẹ, oju opo mi ni @OlayemiOniroyin

E ku ikale


Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment