E duro na, kini ẹsẹ ti Goodluck Jonathan sẹ ti gbogbo eniyan fi n pariwo wi pe awon o fẹ mọ? Ohun to joniloju ju ni wi pe pupọ awon eniyan ti won finu-fidọ dibo fun Jonathan lodun 2011 ni won yari kanlẹ lọtẹ yii wi pe a fi ti awon ba yọ loye bi ẹni yọ jiga danu.
Kini ẹsẹ Goodluck Jonathan gan-an nipato?
Ibeere yii ti mu awon oniroyin wa fon sita lati mọ idi pataki ti awon omo Naija fi keyin si Aare Goodluck Ebele Jonathan ọkọ Patience.
Gẹgẹ bi abọ iroyin se sọ, won ni ọpọlọpọ ọmọ Nigeria se koyin si Jonathan ko tayọ bi Aare se fẹran lati ma hanrun ati fifa lala sẹnu nigba to ba n sun lọ. Won ni ti Aare Goodluck ba hanrun, gbogbo adugbo ni won kii loju orun mọ. Won ni eyi si jẹ ohun pataki ti n bi awon ọmọ Nigeria ninu gidigidi gan-an. Bi o tile je wi pe Aare ni irọ ati ahesọ patapata gbaa ni ẹsun ti won fi kan oun.
"Mo mọ wi pe Tinubu lo wa nidi awon irọ ti won fan kaakiri wi pe mo fọran lati maa hanrun, mo tun gbọ wi pe won ni mo n fa lala sẹnu. Emi kii hanrun o, e le bere lọwọ Iyawo mi to ba dabi irọ. Kosi si ohun ti awon omo Nigeria fẹ ki n se lati fi wẹ ara mi mọ ti mi o le se. To ba jẹ wi pe ki n wa maa sun sile won lọkọọkan ejeeji, mo setan. E sa ba n bewon ki won dibo fun mi. Igbekele ti won naa ko ni ja sofo. Iro ni won pa mọ mi o." oro lati eni Aare Jonathan.
Tọọ, ibi taa ti duro losẹ yii ni fun Abala Iroyin Ti o Common.
E ku faaji
0 comments:
Post a Comment