Smiley face

Won Ti Ranse Pe Oluaye Fuji Ati Omo Re Ni Ilu Amerika

Eni ba le gbemu soke eni o gbemu soke. Oro awon agba ti mo dimu lemi gba logidi oro: won ni "eni foju doba awowo a wo". Oba Fuji asiko yii ko yato soba alaye.

Lara ajoyo ayeye ojo-ibi oba Fuji, King Wasiu Ayinde Marshal omo Anifowose ti n mura lati lo sere Arabambi fun awon ti ilu Amerika.

Aridaju ti wa lati odo Mike Fash, alase Orbit Entertaiment wi pe ibi meji ni Oluomo of Lagos yoo ti maa sere ni ilu Amerika.

Akoko ni eyi ti o se ni Gladyet Banquet to wa ni Brooklyn ni New York lojo keji osu kerin odun taa wa yii (April 2, 2015). Ibi keji ti Baba Yomade yoo tun ti maa korin ni Amazura Concert Hall lojo keta osu kerin (April 3, 2015).

Yara pe fun ankara ti e ni kiakia.

Olu Aye Fuji @ 58, Amerika oteyii ma gejegbe!

Mo tun gbo wi pe omo Wasiu Ayinde Marshal to je olorin takasufe, Honey B naa maa wa ni ilu Amerika pelu baba re lati da awon eniyan lara ya.

Yato si Honey Zainab Marshal ti gbogbo eniyan mo si Honey B, Eniola Badmus (Gbogbo bis Gurl) ati Rasaq Ajao (Ara Osan) naa maa wa nibe pelu.

E je ka pade ni New York City

Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment