Smiley face

Morufa Eko 1: "Mo Kabamo Wi Pe Mo Wa Si Ilu Eko" - Morufa

Oshodi
Sii Olootu,

Olayemi Oniroyin, mo ki yin pupo fun bi e se n gbe ede Yoruba laruge nipase awon iroyin yin. Omo ilu Ibadan ni mi, ni agbegbe Amuloko si ni awon obi mi n gbe. Mo je omobirin eni odun metalelogbon (33) bayii.

Mo ni awon iriri igbe aye mi kan ti mo fe gbe saye, boya lara siso die lara ogbe ati edun okan mi jade, o seese ki okan mi fuye ki alaafia si de ba emi mi. Jugbogbo re lo, o damiloju wi pe awon eniyan yoo tun ri ogbon kan tabi meji ko nibe.

Mo le ma lanfaani lati ko gbogbo alaye mi leekan soso, sugbon maa gbiyanju ibi Olorun ba le ran mi lowo de. Inu mi o si dun ti e ba le maa ran mi lowo nipa atunse si awon leta mi-Yoruba kiko mi ko dan moran daada- ko to di wi pe yoo de ojutaye.

Olorun ologo julo yoo tunbo maa se aleekun ogbon ati agbara fun yin. Amin.

E je n pada sibi alaye mi ti mo n baa bo. Morufa Yekeeni gan-angan ni oruko mi. Awon eniyan ti won mo mi, sugbon ti won kii gbe l’Eko ni won mo mi si Morufa Eko. Sugbon Morufa lo fee gbajugbaja julo.

Igba ti mo wa ni omo odun metadinlogun, leyin igba ti mo pari iwe ile eko girama ni okan ninu awon anti mi kan wa mu mi lo si ilu Eko lati lo se ise aje. Awon obi mi faramo, inu emi naa si dun sii. Anti mi ohun so wi pe ti mo ba de ilu eko ohun to ba wu mi ni mo le pinnu lati maa se. Boya ki n koko ko nipa bi won se n ranso ati bi won ti n se n se keeki akara oyinbo. O ni mo si le ko nipa irun oge sise nitori awon nnkan bee n ta l’Eko. 

Anti mi ti mo wi yii gan-an kii se omo iya mi gan-an, okan ninu awon omo egbon moomi mi. Ajumobi o kan taanu, eni ori ba ti ran sini nii se ni loore. Iya mi a maa ta awon ere oko bi osan, agbado, ata, ogede ati beebee lo, nigba ti baba mi mo n sise ode eran pipa ati agbe.

Ope pupo kii iya mi to se abiyamo. Gege bi ohun ti mo gbo, leyin igba ti won tese ile bo oro naa, won ni asise airomobi naa wa lati owo baba mi nipa ise ode eran pipa re. Oro naa ko ye mi daada, sugbon o dabi eni wi pe baba mi ti pa eran abami ti ko ye ki won o pa ri, sugbon ti won se bee nipase agbara to wa lowo won. Tabi ko je wi pe baba mi se aida si anjannu inu igbo. Fun awon ti won ba maa n gbo eto ode akoni ti won maa n se lori redio Ipinle Oyo, baba mi ti wa sori eto yii ri gege bi alejo pataki.

Igba ti iya mi o tun pada finu soyun, eemeta otooto ni omo ku mo iya mi lowo. Sugbon nigba to ya, Olorun se iyanu, iya mi bi omokunrin kan ti oruko re n je Fatai Durojaye Yekeeni. Leyin eyi ni emi naa wa saye, kosi wahala kankan mo fun dile mi. Baba mi ti kole ojule mejo, ise ode ati agbe naa si egbon mi n se pelu baba mi.

Oshodi ni anti mi to mu wa si lu Eko n gbe, ibe naa lo si ti n sise ounje tita. Ati kekere lo ti nife mi bi oju kii si fe ki enikeni fowo kan mi tabi ba mi wi. Igba to di pe o loko lo wa si ilu Eko. Ise alapata si ni oko re n se. Omo ilu Ibadan naa ni oko re. Anti mi bimi wi pe iru ise wo lo wu mi se. Sugbon ka ma puro, emi gan-an ko tile le so pato nigba naa. Boya ise aso riran ni abi irun sise?

Sugbon ninu okan mi, ise olopa yellow fifa wumi pupo. Eniyan o kan duro loju popo maa pawo rele lojoojumo. walahi mi o gbodo sise un ki n mo kole laarin odun kan. Sugbon, eniyan mo bi ise yellow fifa se ri l’Eko yii sa nibi awon omo oloko ti won ti fagbo yo keri, ti oju won ranko bi ogidan ololaaju. Ju gbogbo re lo, talo fe ba mi wa ise yellow fifa? Ise to tun sun moo ni ise kansu, owo ojumo nigbogbo re dale lori. Ka gba owo ori, ka gba owo lowo awon iya oloja, ile ti won ba ti n se idoti ki n ja tikeeti fun won tabi ki won tun omoluabi won se.

Nigba ti mi o si ti mo ise ti maa se, mo n tele anti mi lo soja lati lo maa ran-an lowo nidi ise ounje tita ti won se. Anti mi ni omo ise kan ti n ran won lowo, iyun je bi igbakeji won pelu omo tapa kan ti ma n ba won fo abo. Awon akoko ti anti mi o ba si l’Eko, boya won wa si Ibadan, igbakeji won a si mo se gbogbo kokari oja won, sebi won ti jo wa se die. Sugbon pelu emi, a di merin. Sebi karin ka po, yiye ni i ye ni.

Anti mi ti bi omo kan nigba naa, itoju omo naa si ti wa lowo mi. Omo yii ni emi a koko toju laaro, ti n si mu lo si ile iwe ki n to lo ba anti mi niso. Idaji si ni oko won ti mo n ji jade. To ba ti di osan ni nnkan bi ago kan, maa gbe ounje osan lo fun oko anti mi nigba to je wi pe inu oshodi naa ni iso tie naa wa. Ti mo ba kuro nibe ni maa lo mu omo won ni ile iwe wa si iso anti mi.

Bi anti mi se n se si mi, ati ife ti mo ti n ni si ise ounje tita, mi o tile ranti ipinnu lati ko ise kankan mo. Nitori Anti mi ti bere si ni sanwo fun mi loseese lati maa toju pamo. Eleyii ti emi naa fi le da ise temi sile leyin ti mo ba kuro lodo anti mi.

O n wa owo lo, o pade iyi lona, to ba ri owo naa ki lo fe fi ra. Se bi ki n le daduro naa ni mo fi fe lo kose. Nigba ti mo si ti n kose ounje bayii ti won tun sanwo fun mi, e wo lo tu ku? Oko anti mi tun je eniyan to naisi pupo gidigidi, koda, aseju wo. Gbogbo igba ni mo n fun mi lowo ti mo ba ti gbe ounje lo fun un niso re, to ba fun mi lowo tan aa ni ki n ma je ki anti mi mo, ko ma baa da eyi ti o fun mi duro. Inu mi o dun, ma si dupe dupe lowo oko anti mi.

Sugbon leyin osu meta ti mo ti n gbe pelu anti mi, isele kan    waye lojo kan eleyii si ba mi lokan je bakan naa ni mo si kabamo wi pe mo wa si ilu Eko.

Mo sese bere si ni ko leta mi ni. Eni a si n gbe iyawo bo wa ba, kii gbe ori iganna woran. Gbogbo alaye ni mo si ti pinnu lati so ke e le fi temi kogbon sugbon oniye abala leta ti mo le fi ranse kii eru mo baa wo ogede ju bo ti ye lo. Maa ro yin ki e pade mi ninu leta mi tuntun ti mi o ni pe fi ranse laipe lati ka gbogbo ibi oro pada yori si.

Isele wo lo sele si mi leyin osu meta ti mo de Ilu Eko?
Talo fa sababi isele naa?
Ki lo fa ti mo fi kabamo wi pe mo wa si ilu Eko?

Gbogbo alaye yii ni e o gbo pata ninu leta mi ti n bo lona.

Emi ni ti yin ni tooto,
Morufa Yekeeni ti inagije re n je Morufa Eko.


Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

7 comments:

  1. Akosile nan da pupo, emi reti apakeji maje ko pe rara

    ReplyDelete
  2. Akosile nan da pupo, emi reti apakeji maje ko pe rara

    ReplyDelete
    Replies
    1. Leta Morufa Yekeeni 2… Oko Anti Mi Fa Idi Mi Ya Perepere
      http://www.olayemioniroyin.com/2015/06/leta-morufa-yekeeni-2-oko-anti-mi-fa.html

      Delete
  3. Olorun o maa fun yin se. E jo e ba wa so fun won ki won tete fi leta naa ranse

    ReplyDelete
  4. Nikete ti won ba ti fi ranse naa la o je ki e ri leta naa ka. Sugbon, a ko ti gbo tuntun lati odo won titi di akoko yii. E se pupo fun awon iriwisi yin. Mo dupe gan.

    ReplyDelete
  5. Olayemi Oniroyin, a n gbadun yin oooo. Ilu Germany ni emi n gbe. Ilu mii si maa dun lati maa ka awon ede abinibi ile wa. God bless you.

    ReplyDelete
  6. Leta Morufa Yekeeni 2… Oko Anti Mi Fa Idi Mi Ya Perepere
    http://www.olayemioniroyin.com/2015/06/leta-morufa-yekeeni-2-oko-anti-mi-fa.html

    ReplyDelete