Smiley face

"Ise Ti Tan!" Talo So Bee? Tani Won So Si? Iru Ise Wo Gan-an Lotan?

Iroyin isale yii ni Ogbeni Yanju Adegboyega gbe sita lori Iku Jackie Chan eleyii ti iroyin naa pada ja nidi leyin ofintoto. Boya eyin o mo eni ti Yanju Adegboyega je, okan pataki lara awon olootu iwe iroyin Alariya Oodua ni i se. Eleyii to mu wa gba wi pe oga oniroyin ni i se. Ki n to tesiwaju, e ja ka ka iroyin ti Ogbeni Yanju Gbe sita.
 
 "Iroyin a gbo sogba nu!!!

Jackie Chan jade laye laaro yii.
Gbajumo okunrin osere nni, Jackie Chan ti ku laaro yii o.

Okunrin ilu-mo-on-ka to ti ko oruko funra re ninu iwe itan
nipase ipa to ko ninu sinima kan, Rumble in the Bronx lodun 1995 ni gbogbo awon ololufe ere sinima lagbaaye gba tie pupo. Iwa ikoni mora re lo fun un loore-ofe lati le gbe ise to yan laayo naa d'oke gege bi, onkorin, opidan, onkowe, adari ere ati osere.

Ise-ise okunrin omo bibi ile China to niyi kaye naa pari laaro yii nileewosan kan niluu Hong Kong nigba ti okan re kose sile.

Akosile awon onisegun oyinbo fi han pe, okan okunrin yii sadeede da'se sile. Eyi ti ko je ko see se fun un lati gbe eje lo sinu opolo atawon eya-ara to se koko lara re. Eyi to si mu opin de ba igbe aye okunrin eleyinju-aanu ohun, eni ti won sapejuwe re gege bi eni to se itore-aanu julo lodun to koja ni orileede re.

Iyawo re, Lin Feng-jiao lo tufo iku Chan nibi ipade akoroyin kan ni bii wakati meloo seyin. Nibi to ti so fawon akoroyin pe, “Mo lero pe adanu to se mi yee yin, inu mi yoo si dun, tee ba le fun wa laaye lati daro”.

Titi d'asiko yi, eto isinku re ko tii ye enikeni. Sugbon, ju gbogbo re lo, won yoo sin oku Jackie Chan segbee awon awon obi re. To koo ni eko itumo ife si molebi re.

Ko si ani-ani pe, adanu nla ni. Maa gb'orun sogo Jackie Chan."




Iroyin ti Yanju Adegboyega fi ede Yoruba to gbamuse gbe jade yii jo bi eni wi pe ko ba ibi todun lara awon akegbe re ti won jo n se ise iroyin. Lara awon oniroyin to koko da lohun ni David Ajiboye, eni to ti fi igba kan sise pelu iwe iroyin Tribune to wa ni ilu Ibadan, eleyii to tako iroyin naa wi pe ko ri beere rara. Oro naa tun gbinaya nigba ti Ogbeni Muyiwa Adekunle ti gbogbo eniyan mo si Bubble Master foju ganni atejade naa. Bubble Master je sorosoro ori redio ko to di wi pe o koja lo si ilu London. Igba to tun de ilu London, Naija FM lo sokale si nibi ti won tun ti de lade Sorosoro ori redio to gbamuse.

Gege bi akiyesi mi, ohun to ba awon eniyan yii lokan je gan-an kii se nipa iroyin eleje ti ko lese nile naa bi ko se wi pe won ko lero wi pe agbalagba oniroyin bi Yanju Adegboyega le gbe iru iroyin bee jade. Gege bi akosemose, igbagbo won ni wi pe n se ni o ye ki ogbeni Yanju se iwadii leyin ti iroyin naa te lowo ko to di wi pe iroyin naa yoo ti owo re jade si ara ilu.

Ise iroyin je ise elege, eniyan si gbodo deju sile daada lati rimu. Ko si eni to koja asise (ati emi gan-an), sugbon oniroyin ko gbodo fi aaye sile fun "Olaju" lati mu dale imule ise iroyin sise.

Kini olaju tunmo si ninu ise iroyin?
ki si ni  imule ise iroyin?

Nipase ayeluja tabi ohun elo ero igbalode, aimoye awon eniyan ni won le se ise iroyin lai je wi pe akosemose ni won. Opolopo won si gba wi pe ohun ti ise iroyin dale ni nipa jije eni akoko ti yoo kede iroyin to ba sele. Latari bee, opolopo yoo maa fonto si araye loju ti won yoo si sebi ise iroyin ni won se. Oniroyin ti ko ba kiyesi daada niru awon akoko bee le tika re bo inu panpe (pakute), eleyii ti o si fe mu dabi eni ti ko koju osun. Eyi wa lara ohun akoba ti olaju mu wo inu ise iroyin sise.

Lara ibura ti won se fun awon oniroyin ki won to bo si agbami ise iroyin leyin ti won ba keko tan ni ileri ati wa otito ohun gbogbo dajudaju laifi igba kan bokan ninu ki won to gbe ise iroyin won jade. Koda, ti iya ba so fun omo re wi pe ohun nife omo oub denudenu, ohun ti ilana ati ofin ise iroyin so ni ki iru omo naa se iwadii boya otito ni oro naa.

Bubble Master so wi pe "ise ti tan." Nje lotito ni wi pe ise Iroyin ti tan?


E joo, maa royin ki e ka Igbe Aye Wale Dada Gege Bi Oniroyin
Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment