Smiley face

Awon Senator Ti Ko Ara Won Lo Si Ile Ejo Lori Oro Bukola Saraki

Sebi won ni ti oke o ba lo ba Momodu, Momodu yoo si dide lo re e boke. Ohun ti awon omo ile igbimo asofin agba ti won n se olooto si Ahmed Lawan, eni ti egbe APC fe ko je Aare ile igbimo asofin se ni yii nipa gbigbe ejo won lo siwaju ile ejo to gaju lo ni ilu Abuja.

Leyin abajade iwadii ile ise olopa nipa bi awon kan se lo towo bo iwe ofin ilana ati agbekale nipa yinyan awon oloye agba ile igbimo, eleyii ti won se lati je ki iyansipo Bukola Saraki omo Baba Oloye rorun ni awon senato ti Ahmed Lawan ko sodi ti lo te pepe re si iwaju ile ejo.

Igbese yii lo waye lana ojo Aje (27-07_15) nibi ti won ti n ro onidajo wi pe ki o gbegi le eto idibo iyansipo Aare ile igbimo asofin agba, Bukola Saraki ati igbakeji re, Ike Ekweremadu.

Sugbon gege bi oro Senator Abiodun Olujimi, omo egbe PDP ti n soju Guusu Ekiti, iya yii ni enikeni ko yii iwe ofin ilana, atunse lasan ni won se sii. Ati wi pe ki Ahmed Lawan ati awon akegbe re lo sempe titi ti yoo fi kan won. Mama yii tun tenu mo wi pe, igba akoko ko ni yii ti won yoo maa se atunse si iwe ofin yii. Eleyii kii se tuntun, ti gbogbo won wa gbe sori bi Wyclef.

Nibayii, aridaju ti wa bayii wi pe oro naa ti wa ni ile ejo, ohun ti gbogbo eniyan n reti ni iru idajo ti onidajo fe da eleyii ti yoo juwe ibi a n re lori rugudu ti n waye ni ile igbimo asofin agba Abuja.

Awon omo ile igbimo asofin agba yoo maa joko lonii (28-07-14) lati te pepe awon oro to wa ni iwaju ile.
Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment