Aare Muhammadu Buhari sese pari ipade pelu awon omo egbe APC ti won wa ni ile igbimo asoju sofin nipa rugudu ti n waye nibe to ni i se pelu taani-yoo-je-olori awon omo egbe to poju.
Saaju igba yii wa, Ogbeni Femi Gbajabiamila ni egbe APC fe ko je olori ile sugbon Yakubu Dogara lo ledi apopo pelu awon omo egbe PDP ti ipo naa si bo sii lowo.
Nibayii, egbe tun fe ki Yakubu Dogara fara mo aba egbe lati je ki Ogbeni Femi Gbajabiamila je olori awon omo egbe to poju sugbon to tun ni beeko.
Oro yii ni Aare tori re pe won lale oni (27-07-15) ninu ile ijoba apapo to wa l'Abuja eleyii ti Dogara tun ni ko le posibu.
Awijare Yakubu Dogara naa ni wi pe, igbakeji oun, Yusuf Lasun, wa lati Goosu-iwo-oorun, yoo nira lati yan Femi Gbajabiamila si iru ipo alagbara yii nigba ti ohun naa wa lati Goosu-iwo-oorun.
Yusuf Lasun si ti fi ake kori wi pe oun ko ni kowe fi ipo oun sile laelae nitori eniboodi. O ni won ti toje bo oloosa lowo, ko si babanla eni to le bo.
Ninu oro Buhari, o ni ko wu oun lati dasi oro ile igbimo asoju sofin, sugbon kii se didun inu oun lati ri wi pe egbe PDP n ri agbara lo nipa taani yoo di ipo mu ninu isejoba to wa lode eleyii ti egbe APC jiya fun.
Ati wi pe ojuse oun ni lati ri wi pe ase egbe mule.
Ipade naa ko yori sibi kan to se koko pelu bi Buhari se ro Dogara, Gbajabiamila ati alaga egbe APC apapo, Odigie-Oyegun lati jo fikunlukun ko to di aaro ola lati le jo gunle si ebute itesiwaju.
Nibi ni Buhari oko Aishatu ti gbe dide wole lo to si fi eyi to ku sile fun won lati yanju.
Awon omo Ile igbimo asoju sofin yoo maa joko lola (28-07-2015).
Subscribe to:
Post Comments
(
Atom
)
0 comments:
Post a Comment