Aare ile yii nigba kan ri, Olusegun Mathew Okikiola Aremu Obasanjo,
so ninu iwe-itan-ara-eni to pe ni "My Watch" wi pe adura iku ni omo oun
gba fun oun nigba ti oun wa loye gege bi Aare ile Nigeria.
Sugbon si ogo Olorun, oun se odun mejo lai fi ese lasan ko.
Gege bi alaye Baba Iyabo ti gbogbo eniyan tun mo si
Ebora ti Ilu Owu se se alaye re. O ni saaju eto idibo odun 1999 ni oun
pe awon agba omo ohun jo ni ilu New York ti ohun si so ero okan oun fun
won lati dije fun ipo Aare.
O ni ibi ti oun ti n soro yii ni Iyabo ti ta peerepe bi adiye ti asa fe gbe omo re salo pelu ariwo.
'Mo mo wi pe oju yin wa nibi oselu, te e ba si se, e ku danu lasan ni. Te e ba si ku, mi o ni sukun yin rara"
"Mo so fun wi pe ti mo ba ku to ba sunkun, o sunkun fun ara re lasan ni nitori wi pe oju mi o teyin mo"
"O je ohun iyalenu wi pe leyin odun mewa ti Iyabo soro
naa, o pada se oselu di senato. Sugbon mo dupe lowo Olorun wi pe mo se
odun mejo lai fese ko."
0 comments:
Post a Comment