Ohun ti eniyan mo laye ni n se apere ibi ti eniyan ti de ri, ohun ti eni naa ti gbo ati oun to fi oju re ri. Idi ni yii ti Yoruba fi n wi pe airinjina lairi abuke okere. Ti eniyan ba rin siwaju yoo ri ibi ti won ti n fodo ibile jeun.
Ni ori oke kan legbe ilu kan ti n je Kunming to wa ni Guusu orileede China ni awon Arara kan ko ara awon jo si ti won si se bee so ibe di ilu nla eleyii ti okiki re ti bere si ni kan kiri agbaye bayii.Ilu awon arara yii ni Oba alade, bee ni won ni oloye laafin, awon olori oba koja keremi. Bakan naa ni won ni olopa onikondo lowo, won ni dokita ti won, won si awon osise panapana nitori ijamba ina.
Aimoye awon eniyan ni won wa kaakiri agbaye bayii lati wa se abewo si won, ati lati mo bi won se n gbe igbe aye won. Pupo ninu awon arin irin-ajo-afe ni won ti beere si ni koja lo silu China lati foju ganni ilu awon arara ti won pe ni Dwarf Empire eleyii ti won da sile lodun 2009.
Bi eniyan ba fe maa gbe ninu ilu naa, eniyan naa ko gbodo gaju iwon ese bata merin lo.
Awon eniyan yii n gbe papo pelu ogidi ife otito, ayo ati idunnu, ko si wi pe enikan n se yeye enikan tabi foju tembelu enikeji, sebi aparo kan ko ga jukan lo.
Bi e ba fe fi iroyin yii sowo si awon eniyan yin, ki won le mo nipa ilu
awon arara. Linki isaleyii ni kee seda re, ki e si fi sowo si won. E maa
si gbagbe lati pade mi lori ero twitter loju opo @OlayemiOniroyin fun
awon iroyin ti n gbona felifeli.
Copy This Link: http://www.olayemioniroyin.com/2015/07/e-wa-wo-ilu-awon-arara-won-loba-won-ni.html
0 comments:
Post a Comment