Leyin iroyin ise iwadii nipa iwosan ara eleyii ti alubosa n se. Ti eyin ko ba ti ka iroyin naa, e le ka a [NIBI]. Aimoye awon eniyan ni won ti n pe mi lori ago fun awon ibeere kan tabi meji.
Mo wa ro wi pe, kilode ti mi o le pada sori alaye naa fun idahun si awon ibeere ti awon eniyan ti n bi mi.
Akoko naa, ki i se agbalagba nikan lo le lo alubosa yii, bikose omode ati agbalagba. Kosi ewu kankan to ro mo lilo alubosa fun iwosan ara gege bi ati se salaye re NIBI. Sebi gbogbo wa naa ni a n je alubosa.
Ekeji ni wi pe ESE MEJEEJI ni e o fi alubosa naa si nigba ti e ba fe sun lale.
Awon kan tile n beere wi pe kini ibasepo alubosa ati atelese eniyan. Awon eroja kan wa ninu alubosa eleyii to ni agbara lati fa arun tabi kokoro jade kuro ninu afefe tabi lara eniyan to wa ni agbegbe naa, ti yoo si fa iru awon nnkan bayii sinu ara re. Idi ni yii ti awon onisegun oyinbo fi so wi pe ko dara ki a maa je alubosa ojo keji ti won ti fi obe bu tabi eyi ti won ti ge kale.
Nitori iru alubosa bee yoo ti fa gbogbo arun tabi kokoro to ba wa ni agbegbe naa sinu ara re. Ti eniyan ba wa je iru alubosa bee bi igba ti eni naa tun je aisan sinu ara re ni.
Alaye nipa atelese eniyan, gege bi alaye awon onimo isegun oyinbo to danto, gbogbo eya ara pata lo ni asoju ni atelese eda. Tabi ki n so wi pe gbogbo eya ara lo ni asopo pelu atelese eniyan. Idi ni yii to fi ye ko je wi pe atelese ni a fi alubosa naa si, ki agbara iwoasan naa le kari gbogbo ara wa pata.
Mo tile tun ri gbo wi pe eniyan tun le fi alubosa ayu (garlic) die kun
alubosa naa ko tun le mu ise re lagbara sii. Sugbon ti eniyan ko ba ri ayu, alubosa lasan naa le sise daada ti alaafia yoo tun de ba ago
ara.
E je ka wo ohun ti Dokita Lauren Feder lati ilu Los Angeles so nipa alubosa lilo fun iwosan ara eda.
Dokita Lauren Feder |
“For colds, an onion pouch in [a] room can help with congestion,” o tun salaye siwaju. “In addition to treating colds, onion socks can be used for earaches, teething, and bladder infections.” - Dokita Lauren Feder http://www.drfeder.com
Ire o!
0 comments:
Post a Comment