Awon Yoruba bo, won ni agba kii wa loja ki ori omo tuntun o wo. Sebi ti omode ba si laso bi agba, o daju wi pe ko le ni akisa bi agba laelae. Ohun ti agba ri lori ijoko, tomode ba gun akaba ko le ri i rara.
Yoruba naa lo tun so pe a kii so wi pe oju agba jin, sebi oni ohun tagba ti ri koju to ko wonu.
Taba n so nipa awon asaaju ninu ede Yoruba, Olatunbosun Oladapo ti awon kan tun mo si Odidere Ayekooto ti kuro leni ti won le foju pare ninu imo-ogbon ede Yorubaawa.
Ninu alaye baba naa, baba yii gba wi pe ona ti awon eniyan n gba lo "Abenugan" ati "Alukoro" je asilo ninu ede Yoruba.
Alaye Baba naa ni yii:
"EDE ABUKU NI ABENUGAN....AWON ELENUUGBORO NI YORUBA N PE NI ABENUGAN... ...OLUDARI TABI ALAGA ILE IGBIMO AWON ASOFIN WA ...WON KI I SE
ABENUGAN ELENUUGBORO......
. ......BAKAN NAA.....ENI TO BA N WA NI NIJA...TO BA N FINRAN...NI YORUBA N PE NI ALUKORO...AWON P R O KI I SE AWANI NIJA..WON KI I SE OFINRAN....ALARINA NI WON...EYIN OJOGBON ATI AKOWE ATI GBEDEGBEYO ATI SOROSORO....E FI OJU AGBA WO AWON GBOLOHUN MEJEEJI YEN OOO.....ABENUGAN ATI ALUKORO....
IRE OOO". Olatunbosun Oladapo
Odun 1970 ni Olatunbosun Oladapo gba ise sorosoro lori redio ati telifisan WNBS/WNTV. Igba to di odun 1977 lo kowe fi ise sile lati da ile ise ara re sile eleyii to pe ni Olatunbosun Records Company.
Orisirisi olorin ibile ni baba yii ti gbe jade bi Odolaye Aremu,Yekini Ajao, Ayanyemi
Atokowagbowonle, Remi Olabamiji, Micho Ade, Ogundare Foyanmu ati bee bee lo.
Aimoye awo orin ibile to je ise owo baba gan-angan naa ni baba ti fun ra re gbe jade fun igbelaruge ede ati asa Yoruba.
Ilu Ibadan ni baba n gbe, sugbon Ifafiti ilu Eko lo ti keko gboye ninu ede Yoruba pelu sabuke to peregede.
0 comments:
Post a Comment