Owo awon olopa Ipinle Benue ti te okunrin kan ti oruko re n je Raphael Agazi eleyii to ge ori okunrin ti oruko n je Ajah Esim. Titi di akoko yii, enikeni ko le so pato ohun to mu odaran naa wu iru iwa ika-odaju bee.
Ni agbegbe kan ti n je Ijekun to wa ni ijoba ibile Obi ni Ipinle Benue ni owo awon olopa ti te Raphael Agazi pelu ori eniyan to gbe pamo sinu apamo dudu.
Ko jewo ohun to fe fi oriolori se, sugbon awon olopa fura wi pe oseese ko fe lo ta ori eniyan naa ni, nitori awon iwa ibaje bee wopo ni agbegbe Ijekun.
Sugbon nigba ti awon olopa tun se iwadii siwaju sii, won tun rigbo wi pe okunrin odaran yii ati eni ti won pa jo n du ile (land) kan mo ara won lowo.
Ojo Aje to koja yii ni awon mejeeji si jo pade lori ile naa eleyii ti ipade won yori si ijakadi.
Won ni o seese ko je igba naa ni odaran ti seku pa Ajah Esim to si ge ori re kuro lara re.
Owo awon olopa ti te Raphael Agazi to seku pa Ajah Esim. Won si ti lo wu iyoku ara Ajah Esim nibi ti odaran naa bo mo.
Ibere ti enikeni ko mo idahun re naa ni wi pe, kini pato ohun ti Raphael Agazi fe lo fi ori Ajah Esim to pa se?
Okunrin yii ko lati jewo, ko soro, oju re da gbau, bee ni wo rakorako bi esu ti jeun lorita meta.
0 comments:
Post a Comment