Smiley face

Odun Eegun Agbomola Ni Ilu Spain

Awon Yoruba bo, won ni idalu ni iselu. Eegun ni i gbowo ode nilu Oshogbo Oroki omo asala. Lara asa awon eniyan ilu Spain ni odun El Colacho eyi ti won tun mo si odun fifo koja lori awon omo tuntun eleyii to maa n waye ni Burgos, ni ariwa ilu Spain.

Odun 1620 ni itan so fun wa wi pe won ti bere orisi odun yii, eleyii to si wa titi di oni.

Awon omo tuntun ti won ba bi lati nnkan bi osu mejila seyin nigba ti odun naa fi waye ni awon obi won yoo te won sile lo loju titi. Ti awon okunrin ti won mura bi eegun yoo si bere si ni fo won koja.

Enikeni ko le so pato ohun to fa sababi iwaye odun yii sugbon igbagbo gbogbo eniyan ni wi pe odun yii ma n we ese (sin) awon omo kekere danu, ko si ni je ki won se aisan tabi ki agbara aye ka won. 

Sugbon sa, awon elesin igbagbo tako asa naa gidigidi. Won ni iribomi tabi itebomi nipa Jesu omo Olorun nikan lo le we ese eniyan nu kii se nipa fifo koja lori awon omo wewe.


Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment