Ki ise iroyin to di gbajugbaja, awon olorin ni won mu ise iroyin mo ise orin kiko.
Nigba laelae, awon olorin maa n korin lati ileto bo si ileto, lati ilu kan bo si ekeji.
Nipa sise bayii, pupo awon isele manigbagbe tabi isele to ba kanilaya to waye ni ilu ibi ti won ti korin seyin maa n jeyo ninu orin won.
Ti oba tuntun ba je tabi ti oba ba waja;
Ti ile tabi oko ba jona;
Ti eniyan pataki ba bimo tabi gbe iyawo tuntun abbl.
Awon nnkan wonyii maa n jeyo ninu ise orin won gege bi iroyin.
Orisirisi itan mii tun le romo ibeere pepe ise iroyin sise.
Gege bi apere, awon eniyan le gbo nipa ohun to ti sele tabi eyi ti n sele lowolowo ni awon apa agbegbe kan ni ojo awon oja nla to wa laye atijo.
Orisirisi awon eniyan ni won maa n wa lati orisirisi ileto ati ilu lati wa naja, ti iroyin isele okeere si le di mimo fun awon eniyan ti won wa na oja lati apa ibomii.
Sugbon iru awon iroyin bayii ko lokun nidi, pupo ninu won lo si gunle ofofo, aheso tabi gboyisoyi.
Gege bi olorin, o daju wi pe awon eniyan yoo pe oruko re mo ohunkohun to ba ti enu re jade. Idi niyii ti awon eniyan fi ni igbagbo ati idaniloju ninu iroyin awon olorin. Eyi wa lara awon iroyin to lokun nidi yato si eyi taa gbo laarin oja nla.
Bi o tile je wi pe awon olorin ko ko ise iroyin sise, sugbon won ri ise iroyin sise gege bi ojuse won si awujo lati je ki awon eniyan mo nipa ohun to n lo ni agbegbe tabi ayika won.
Kosi si bi eniyan yoo se ka awon abuda orin lai menu ba iroyin yato si idaraya, ikilo, waasu, iyanju ati idanileko eleyii to je laarija awon eroja ti eniyan yoo ba pade ninu orin.
Pelu awon alaye kekere yii, ti e ko ba duro lati ka apakeji alaye mi, o seese ke gba wi pe Olorin loga Oniroyin. Sugbon mi o le fi gbogbo enu so wi pe bee lo ri.
@OlayemiOniroyin loju opo mi lori ero twitter, inu mi yoo dun lati pade yin nibe.
E ku ikale!
0 comments:
Post a Comment